Sáàmù 12:1-8

  • Jèhófà dìde láti gbé ìgbésẹ̀

    • Àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ́ (6)

Sí olùdarí; kí a yí i sí Ṣẹ́mínítì.* Orin Dáfídì. 12  Gbà mí Jèhófà, nítorí kò sí ẹni ìdúróṣinṣin mọ́;Àwọn olóòótọ́ ti pòórá láàárín àwọn èèyàn.   Irọ́ ni wọ́n ń pa fún ara wọn;Wọ́n ń fi ètè wọn pọ́nni,* wọ́n sì ń fi ọkàn ẹ̀tàn* sọ̀rọ̀.+   Jèhófà máa gé gbogbo ètè tó ń pọ́nni kúròÀti ahọ́n tó ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga,+   Àwọn tó ń sọ pé: “Ahọ́n wa la máa fi ṣàṣeyọrí. Bó ṣe wù wá ni à ń lo ètè wa;Ta ló máa jẹ ọ̀gá lé wa lórí?”+   “Nítorí ìnira àwọn tí ìyà ń jẹ,Nítorí ìkérora àwọn aláìní,+Màá dìde láti gbé ìgbésẹ̀,” ni Jèhófà wí. “Màá gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn tó kórìíra wọn.”*   Àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà mọ́;+Wọ́n dà bíi fàdákà tí a yọ́ mọ́ nínú iná ìléru tí wọ́n fi amọ̀ ṣe,* èyí tí a yọ́ mọ́ ní ìgbà méje.   Jèhófà, wàá máa ṣọ́ wọn;+Wàá dáàbò bo kálukú wọn lọ́wọ́ ìran yìí títí láé.   Àwọn ẹni burúkú ń rìn káàkiri fàlàlàNítorí pé àwọn ọmọ èèyàn ń gbé ìwà ìbàjẹ́ lárugẹ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “Wọ́n ń fi ètè dídùn sọ̀rọ̀.”
Ní Héb., “ọkàn àti ọkàn.”
Tàbí “tó ń fi wọ́n ṣẹ̀sín.”
Tàbí kó jẹ́, “ìléru tí wọ́n fi ń yọ́ irin, tí wọ́n ṣe sórí ilẹ̀.”