Sáàmù 149:1-9
149 Ẹ yin Jáà!*
Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà;+Ẹ yìn ín nínú ìjọ àwọn adúróṣinṣin.+
2 Kí Ísírẹ́lì máa yọ̀ nínú Aṣẹ̀dá rẹ̀ Atóbilọ́lá;+Kí inú àwọn ọmọ Síónì máa dùn nínú Ọba wọn.
3 Kí wọ́n máa fi ijó yin orúkọ rẹ̀+Kí wọ́n sì máa kọ orin ìyìn* sí i, pẹ̀lú ìlù tanboríìnì àti háàpù.+
4 Nítorí inú Jèhófà ń dùn sí àwọn èèyàn rẹ̀.+
Ó ń fi ìgbàlà ṣe àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ lọ́ṣọ̀ọ́.+
5 Kí àwọn adúróṣinṣin máa yọ̀ nínú ògo;Kí wọ́n máa kígbe ayọ̀ lórí ibùsùn wọn.+
6 Kí orin ìyìn Ọlọ́run wà lẹ́nu wọn,Kí idà olójú méjì sì wà lọ́wọ́ wọn,
7 Láti gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè,Kí wọ́n sì fìyà jẹ àwọn èèyàn,
8 Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn,Kí wọ́n sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn èèyàn pàtàkì wọn,
9 Láti mú ìdájọ́ tó ti wà lákọsílẹ̀ nípa wọn ṣẹ.+
Iyì yìí jẹ́ ti gbogbo àwọn adúróṣinṣin rẹ̀.
Ẹ yin Jáà!*
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
^ Tàbí “kọrin.”
^ Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.