Sáàmù 136:1-26

  • Ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ wà títí láé

    • Ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run àti ayé (5, 6)

    • Fáráò kú sínú Òkun Pupa (15)

    • Ọlọ́run ń rántí àwọn tí ìdààmú bá (23)

    • Ó ń fún gbogbo ohun alààyè ní oúnjẹ (25)

136  Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí ó jẹ́ ẹni rere;+Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.+  Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run,+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.  Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa,Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.  Òun nìkan ló ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu,+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.+  Ó fi ọgbọ́n* dá àwọn ọ̀run,+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.  Ó tẹ́ ayé sórí omi,+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.  Ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá,+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.  Oòrùn láti máa jọba lórí ọ̀sán,+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.  Òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ láti máa jọba lórí òru,+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé. 10  Ó pa àwọn àkọ́bí Íjíbítì,+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé. 11  Ó mú Ísírẹ́lì jáde kúrò láàárín wọn,+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé. 12  Pẹ̀lú ọwọ́ agbára+ àti apá tó nà jáde,Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé. 13  Ó pín Òkun Pupa sí méjì,*+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé. 14  Ó mú kí Ísírẹ́lì gba àárín rẹ̀ kọjá,+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé. 15  Ó gbọn Fáráò àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sínú Òkun Pupa,+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé. 16  Ó mú àwọn èèyàn rẹ̀ gba inú aginjù kọjá,+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé. 17  Ó pa àwọn ọba ńlá,+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé. 18  Ó pa àwọn ọba alágbára,Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé. 19  Síhónì+ ọba àwọn Ámórì,Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé 20  Àti Ógù+ ọba Báṣánì,Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé. 21  Ó fi ilẹ̀ wọn ṣe ogún,+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé. 22  Ó fi ṣe ogún fún Ísírẹ́lì ìránṣẹ́ rẹ̀,Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé. 23  Ó rántí wa nígbà tí wọ́n rẹ̀ wá sílẹ̀,+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.+ 24  Ó ń gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé. 25  Ó ń fún gbogbo ohun alààyè* ní oúnjẹ,+Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé. 26  Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run,Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “òye.”
Ní Héb., “sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.”
Ní Héb., “gbogbo ẹlẹ́ran ara.”