Sáàmù 95:1-11

  • Ìjọsìn tòótọ́ pẹ̀lú ìgbọràn

    • “Lónìí, tí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀” (7)

    • “Ẹ má ṣe mú kí ọkàn yín le” (8)

    • “Wọn ò ní wọnú ìsinmi mi” (11)

95  Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká kígbe ayọ̀ sí Jèhófà! Ẹ jẹ́ ká kígbe ìṣẹ́gun sí Àpáta ìgbàlà wa.+   Ẹ jẹ́ ká wá sí iwájú* rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́;+Ẹ jẹ́ ká kọrin, ká sì kígbe ìṣẹ́gun sí i.   Nítorí pé Ọlọ́run ńlá ni Jèhófà,Ọba ńlá lórí gbogbo àwọn ọlọ́run yòókù.+   Ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ayé wà;Àwọn téńté orí òkè jẹ́ tirẹ̀.+   Òkun jẹ́ tirẹ̀, òun ló dá a,+Ọwọ́ rẹ̀ ló sì dá ilẹ̀ gbígbẹ.+   Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká jọ́sìn, ká sì forí balẹ̀;Ẹ jẹ́ ká kúnlẹ̀ níwájú Jèhófà Ẹni tó dá wa.+   Nítorí òun ni Ọlọ́run wa,Àwa sì ni èèyàn ibi ìjẹko rẹ̀,Àgùntàn tó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀.*+ Lónìí, tí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀,+   Ẹ má ṣe mú kí ọkàn yín le bí ẹ ṣe ṣe ní Mẹ́ríbà,*+Bíi ti ọjọ́ Másà* ní aginjù,+   Nígbà tí àwọn baba ńlá yín dán mi wò;+Wọ́n pè mí níjà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ mi.+ 10  Ogójì (40) ọdún ni mo fi kórìíra ìran yẹn, mo sì sọ pé: “Àwọn èèyàn tó máa ń ṣìnà nínú ọkàn wọn ni wọ́n;Wọn ò tíì mọ àwọn ọ̀nà mi.” 11  Torí náà, mo búra nínú ìbínú mi pé: “Wọn ò ní wọnú ìsinmi mi.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọ̀dọ̀.”
Ní Héb., “ọwọ́ rẹ̀.”
Ó túmọ̀ sí “Ìjà.”
Ó túmọ̀ sí “Àdánwò.”