Sáàmù 97:1-12
97 Jèhófà ti di Ọba!+
Kí inú ayé máa dùn.+
Kí ọ̀pọ̀ erékùṣù máa yọ̀.+
2 Ìkùukùu àti ìṣúdùdù tó kàmàmà yí i ká;+Òtítọ́ àti ìdájọ́ òdodo ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.+
3 Iná ń lọ níwájú rẹ̀,+Ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ run yí ká.+
4 Mànàmáná rẹ̀ mú kí ilẹ̀ mọ́lẹ̀ kedere;Ayé rí i, ó sì ń gbọ̀n.+
5 Àwọn òkè yọ́ bí ìda níwájú Jèhófà,+Níwájú Olúwa gbogbo ayé.
6 Ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀,Gbogbo èèyàn sì ń rí ògo rẹ̀.+
7 Kí ojú ti gbogbo àwọn tó ń sin ère gbígbẹ́,+Àwọn tó ń fi àwọn ọlọ́run asán+ wọn yangàn.
Ẹ forí balẹ̀ fún un,* gbogbo ẹ̀yin ọlọ́run.+
8 Síónì gbọ́, ó sì ń yọ̀;+Inú àwọn ìlú* Júdà ń dùnNítorí àwọn ìdájọ́ rẹ, Jèhófà.+
9 Nítorí pé, ìwọ Jèhófà ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé;O ga fíìfíì ju gbogbo àwọn ọlọ́run yòókù.+
10 Ẹ̀yin tí ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ẹ kórìíra ohun tó burú.+
Ó ń ṣọ́ ẹ̀mí* àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀;+Ó ń gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́* àwọn ẹni burúkú.+
11 Ìmọ́lẹ̀ ti tàn fún olódodo,+Ayọ̀ sì kún inú àwọn tí ọkàn wọn dúró ṣinṣin.
12 Ẹ máa yọ̀ nínú Jèhófà, ẹ̀yin olódodo,Ẹ sì máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́* rẹ̀.

