Sáàmù 5:1-12
Sí olùdarí fún Néhílótì.* Orin Dáfídì.
5 Fetí sí ọ̀rọ̀ mi, Jèhófà;+Fiyè sí ẹ̀dùn ọkàn mi.
2 Fetí sí igbe ìrànlọ́wọ́ mi,Ìwọ Ọba mi àti Ọlọ́run mi, torí pé ìwọ ni mò ń gbàdúrà sí.
3 Ní òwúrọ̀, Jèhófà, wàá gbọ́ ohùn mi;+Ní òwúrọ̀, màá sọ ohun tó ń jẹ mí lọ́kàn fún ọ,+ màá sì dúró dè ọ́.
4 Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tó fẹ́ràn ìwà burúkú;+Kò sí ẹni burúkú tó lè dúró lọ́dọ̀ rẹ.+
5 Kò sí agbéraga tó lè dúró níwájú rẹ.
O kórìíra gbogbo àwọn tó ń hùwà ibi;+
6 Wàá pa àwọn tó ń parọ́ run.+
Jèhófà kórìíra àwọn tó ń hu ìwà ipá àti ìwà ẹ̀tàn.*+
7 Àmọ́ màá wá sínú ilé rẹ+ nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tó lágbára;+Màá forí balẹ̀ ní ìdojúkọ tẹ́ńpìlì mímọ́* rẹ nínú ẹ̀rù tí mo ní fún ọ.+
8 Jèhófà, ṣamọ̀nà mi nínú òdodo rẹ nítorí àwọn ọ̀tá mi;Mú kí ọ̀nà rẹ là fún mi.+
9 Nítorí kò sí èyí tó ṣeé gbára lé nínú ọ̀rọ̀ wọn;Èrò ibi ló kún inú wọn;Sàréè tó ṣí sílẹ̀ ni ọ̀fun wọn;Wọ́n ń fi ẹnu wọn pọ́nni.*+
10 Àmọ́ Ọlọ́run á dá wọn lẹ́bi;Èrò ibi wọn á mú kí wọ́n ṣubú.+
Kí a lé wọn dà nù torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn tó pọ̀ gan-an,Nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.
11 Àmọ́ gbogbo àwọn tó fi ọ́ ṣe ibi ààbò á máa yọ̀;+Ìgbà gbogbo ni wọ́n á máa kígbe ayọ̀.
Wàá dáàbò bo ọ̀nà àbáwọlé wọn,Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ orúkọ rẹ yóò sì máa yọ̀ nínú rẹ.
12 Jèhófà, wàá bù kún ẹni tó bá jẹ́ olódodo;Wàá fi ojú rere dáàbò bò wọ́n bí apata ńlá.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ẹni tó ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ tó sì ń tanni jẹ.”
^ Tàbí “ibi mímọ́.”
^ Tàbí “Wọ́n ń lo ahọ́n dídùn.”

