Sáàmù 73:1-28
Orin Ásáfù.+
73 Ní tòótọ́, Ọlọ́run ṣe rere fún Ísírẹ́lì, fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́.+
2 Ní tèmi, ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ẹ́ yà kúrò lójú ọ̀nà;Díẹ̀ ló kù kí ẹsẹ̀ mi yọ̀ tẹ̀rẹ́.+
3 Nítorí mo jowú àwọn agbéraga*Nígbà tí mo rí àlàáfíà àwọn ẹni burúkú.+
4 Ikú wọn kì í mú ìrora lọ́wọ́;Ara wọn jí pépé.*+
5 Ìdààmú tó ń bá àwọn èèyàn yòókù kì í bá wọn,+Ìyà tó sì ń jẹ àwọn èèyàn tó kù kì í jẹ wọ́n.+
6 Nítorí náà, ìgbéraga ni ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn wọn;+Wọ́n gbé ìwà ipá wọ̀ bí aṣọ.
7 Aásìkí* wọn mú kí ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn yọ;Wọ́n ti ní kọjá ohun tí ọkàn wọn rò.
8 Wọ́n ń fini ṣẹ̀sín, wọ́n sì ń sọ ohun tó burú.+
Wọ́n ń fi ìgbéraga halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn láti ni wọ́n lára.+
9 Wọ́n ń sọ̀rọ̀ bíi pé wọ́n ga dé ọ̀run,Ahọ́n wọn sì ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga káàkiri ayé.
10 Nítorí náà, àwọn èèyàn rẹ̀* yíjú sọ́dọ̀ wọn,Wọ́n sì mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi wọn.
11 Wọ́n ń sọ pé: “Báwo ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ mọ̀?+
Ṣé Ẹni Gíga Jù Lọ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ni?”
12 Bí ọ̀rọ̀ àwọn ẹni burúkú ṣe rí nìyí, àwọn tí gbogbo nǹkan dẹrùn fún.+
Wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ ṣáá.+
13 Ó dájú pé lásán ni mo pa ọkàn mi mọ́,Tí mo sì wẹ ọwọ́ mi mọ́ pé mo jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀.+
14 Ìdààmú bá mi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;+Àràárọ̀ ni mò ń gba ìbáwí.+
15 Ká ní mo ti sọ irú ọ̀rọ̀ yìí ni,Mi ò bá ti dalẹ̀ àwọn èèyàn* rẹ.
16 Nígbà tí mo sapá láti lóye rẹ̀,Ó dà mí láàmú
17 Títí mo fi wọ ibi mímọ́ títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run,Tí mo sì wá mọ ọjọ́ ọ̀la wọn.
18 Ó dájú pé orí ilẹ̀ tó ń yọ̀ lo gbé wọn lé.+
Kí wọ́n lè ṣubú kí wọ́n sì pa run.+
19 Ẹ wo bí wọ́n ti pa rẹ́ lójijì!+
Ẹ wo bí òpin ṣe dé bá wọn lójijì, tí wọ́n sì pa run!
20 Jèhófà, ńṣe ló dà bí àlá nígbà téèyàn bá jí,Nígbà tí o bá dìde, wàá gbé wọn kúrò lọ́kàn.*
21 Àmọ́ ọkàn mi korò,+Inú mi lọ́hùn-ún* sì ń ro mí gógó.
22 Mi ò nírònú, mi ò sì lóye;Mo dà bí ẹranko tí kò ní làákàyè níwájú rẹ.
23 Àmọ́ ní báyìí, ọ̀dọ̀ rẹ ni mo wà nígbà gbogbo;O ti di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.+
24 O fi ìmọ̀ràn rẹ ṣamọ̀nà mi,+Lẹ́yìn náà, wàá mú mi wọnú ògo.+
25 Ta ni mo ní lọ́run?
Lẹ́yìn rẹ, kò sí ohun míì tó wù mí ní ayé.+
26 Àárẹ̀ lè mú ara mi àti ọkàn mi,Àmọ́ Ọlọ́run ni àpáta ọkàn mi àti ìpín mi títí láé.+
27 Ní tòótọ́, àwọn tó jìnnà sí ọ yóò ṣègbé.
Gbogbo àwọn tó fi ọ́ sílẹ̀ lọ ṣe ìṣekúṣe* ni wàá pa run.*+
28 Àmọ́ ní tèmi, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.+
Mo ti fi Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ṣe ibi ààbò mi,Kí n lè máa kéde gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.+

