Sáàmù 120:1-7
Orin Ìgòkè.*
120 Mo ké pe Jèhófà nínú wàhálà mi,+Ó sì dá mi lóhùn.+
2 Jèhófà, gbà mí* lọ́wọ́ ètè tó ń parọ́Àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.
3 Ṣé o mọ ohun tí Ó máa ṣe sí ọ, ṣé o mọ ìyà tí Ó máa fi jẹ ọ́,*Ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?+
4 Yóò lo àwọn ọfà mímú+ jagunjagunÀti ẹyin iná+ àwọn igi wíwẹ́.
5 Mo gbé, nítorí mo jẹ́ àjèjì ní Méṣékì!+
Mò ń gbé láàárín àwọn àgọ́ Kídárì.+
6 Mo* ti ń gbé tipẹ́tipẹ́Pẹ̀lú àwọn tó kórìíra àlàáfíà.+
7 Àlàáfíà ni èmi ń fẹ́, àmọ́ nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀,Ogun ni wọ́n ń fẹ́.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “gba ọkàn mi.”
^ Ní Héb., “kí ni Òun yóò sì fi kún un fún ọ?”
^ Tàbí “Ọkàn mi.”

