Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

Bíbélì Mímọ́ jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà lákọọ́lẹ̀ fún gbogbo wa. A gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ká lè mọ Òǹṣèwé rẹ̀. (Jòhánù 17:3; 2 Tímótì 3:16) Nínú rẹ̀, Jèhófà jẹ́ ká mọ ohun tó ní lọ́kàn fún àwa èèyàn àti ayé tí à ń gbé.—Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Ìfihàn 21:3, 4.

Kò sí ìwé míì tó ń nípa lórí àwa èèyàn bíi Bíbélì. Bíbélì máa ń mú ká ní ìfẹ́, àánú àti ìyọ́nú bíi ti Jèhófà. Ó ń jẹ́ ká ní ìrètí, ó sì ń jẹ́ káwa èèyàn lè fara da ìyà tó le gan-an pàápàá. Ó ń jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tí kò bá ìfẹ́ pípé ti Ọlọ́run mu nínú ayé yìí.Sáàmù 119:105; Hébérù 4:12; 1 Jòhánù 2:15-17.

Èdè Hébérù, Árámáíkì àti Gíríìkì ni wọ́n fi kọ Bíbélì, a sì ti túmọ̀ rẹ̀ lódindi tàbí lápá kan sí ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èdè. Òun ni ìwé tí wọ́n túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù lọ, tí wọ́n sì pín kiri jù lọ látìgbà táláyé ti dáyé. Bó sì ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn, torí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí [kókó tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú Bíbélì] ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.”—Mátíù 24:14.

Torí pé a mọ bí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ti ṣe pàtàkì tó, a mú kí àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ túbọ̀ yéni, a sì fọwọ́ pàtàkì mú ohun tó wà nínú rẹ̀. A gbà pé ojúṣe wa ni pé a gbọ́dọ̀ gbé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ jáde lọ́nà tó péye. Iṣẹ́ ribiribi tí a ṣe sínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tó wà tẹ́lẹ̀, èyí tí a kọ́kọ́ mú jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì ní ohun tó lé ní ọgọ́ta (60) ọdún sẹ́yìn ló mú kó rọrùn láti ṣe ẹ̀dà tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ túbọ̀ yéni yìí. Àfojúsùn wa ni pé ká túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lọ́nà tó péye, tó ṣe kedere, tó sì rọrùn láti kà. Àwọn Àfikún bíi “Ìlànà Tó Wà fún Iṣẹ́ Ìtúmọ̀ Bíbélì,” “Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì Tí A Tún Ṣe Yìí” àti “Bí Bíbélì Ṣe Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́” jẹ́ ká mọ díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ tí a mú kó túbọ̀ yéni nínú ẹ̀dà yìí.

Ó wu àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run tí wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀ pé kí wọ́n ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ìtúmọ̀ rẹ̀ péye, tó sì yéni. (1 Tímótì 2:4) Ìdí nìyẹn tí a fi mú ìtúmọ̀ tó túbọ̀ yéni yìí jáde lédè Yorùbá, ó sì wù wá pé kí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun wà ní èdè púpọ̀ sí i. À ń gbà á ládùúrà, a sì nírètí pé ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ yìí máa ṣe ẹ̀yin tí ẹ̀ ń kà á láǹfààní, bí ẹ ti ń sa gbogbo ipá yín láti ‘wá Ọlọ́run, kí ẹ sì rí i ní ti gidi.’—Ìṣe 17:27.

Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun

December 2018