Sáàmù 145:1-21

  • Ẹ yin Ọlọ́run, Ọba ńlá

    • ‘Màá kéde títóbi Ọlọ́run’ (6)

    • “Jèhófà ń ṣoore fún gbogbo ẹ̀dá” (9)

    • ‘Àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ yóò máa yìn ọ́’ (10)

    • Ìjọba Ọlọ́run tó máa wà títí láé (13)

    • Ọwọ́ Ọlọ́run ń tẹ́ gbogbo ẹ̀dá lọ́rùn (16)

Ìyìn Dáfídì. א [Áléfì] 145  Màá gbé ọ ga, ìwọ Ọlọ́run mi Ọba,+Màá yin orúkọ rẹ títí láé àti láéláé.+ ב [Bétì]  Màá yìn ọ́ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;+Màá yin orúkọ rẹ títí láé àti láéláé.+ ג [Gímélì]  Jèhófà tóbi, òun sì ni ìyìn yẹ jù lọ,+Àwámáridìí ni títóbi rẹ̀.*+ ד [Dálétì]  Ìran dé ìran yóò máa yin àwọn iṣẹ́ rẹ;Wọ́n á máa sọ nípa iṣẹ́ ńlá rẹ.+ ה [Híì]  Wọ́n á máa sọ nípa ọlá ńlá ológo iyì rẹ,+Màá sì máa ṣe àṣàrò lórí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ. ו [Wọ́ọ̀]  Wọ́n á máa sọ nípa àwọn iṣẹ́* àgbàyanu rẹ,Màá sì máa kéde títóbi rẹ. ז [Sáyìn]  Wọ́n á máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bí wọ́n ṣe ń sọ nípa ọ̀pọ̀ oore rẹ,+Wọ́n á sì máa kígbe ayọ̀ nítorí òdodo rẹ.+ ח [Hétì]  Jèhófà jẹ́ agbatẹnirò* àti aláàánú,+Kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.+ ט [Tétì]  Jèhófà ń ṣoore fún gbogbo ẹ̀dá,+Àánú rẹ̀ sì wà lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀. י [Yódì] 10  Jèhófà, gbogbo iṣẹ́ rẹ yóò máa yìn ọ́ lógo,+Àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ yóò sì máa yìn ọ́.+ כ [Káfì] 11  Wọ́n á máa kéde ògo ìjọba rẹ,+Wọ́n á sì máa sọ̀rọ̀ nípa agbára rẹ,+ ל [Lámédì] 12  Kí aráyé lè mọ àwọn iṣẹ́ ńlá rẹ+Àti ògo ọlá ńlá ìjọba rẹ.+ מ [Mémì] 13  Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ,Àkóso rẹ sì wà láti ìran dé ìran.+ ס [Sámékì] 14  Jèhófà ń gbé gbogbo àwọn tó ti fẹ́ ṣubú ró,+Ó sì ń gbé gbogbo àwọn tó dorí kodò dìde.+ ע [Áyìn] 15  Ojú rẹ ni gbogbo ẹ̀dá ń wò,Ò ń fún wọn ní oúnjẹ wọn lásìkò.+ פ [Péè] 16  O ṣí ọwọ́ rẹ,O sì fún gbogbo ohun alààyè ní ohun tí wọ́n ń fẹ́.+ צ [Sádì] 17  Jèhófà jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+Ó sì jẹ́ adúróṣinṣin nínú gbogbo ohun tó ń ṣe.+ ק [Kófì] 18  Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é,+Nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é ní òtítọ́.*+ ר [Réṣì] 19  Ó ń fún àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ ní ohun tí ọkàn wọn ń fẹ́;+Ó ń gbọ́ igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́, ó sì ń gbà wọ́n.+ ש [Ṣínì] 20  Jèhófà ń ṣọ́ gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀,+Àmọ́ yóò pa gbogbo ẹni burúkú run.+ ת [Tọ́ọ̀] 21  Ẹnu mi yóò kéde ìyìn Jèhófà;+Kí gbogbo ohun alààyè* máa yin orúkọ mímọ́ rẹ̀ títí láé àti láéláé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Títóbi rẹ̀ kọjá òye ẹ̀dá.”
Tàbí “nípa agbára.”
Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”
Tàbí “tó ń fòótọ́ inú ké pè é.”
Ní Héb., “gbogbo ẹran ara.”