Sáàmù 65:1-13
Sí olùdarí. Orin Dáfídì. Orin.
65 Ọlọ́run, ìyìn ń dúró dè ọ́ ní Síónì;+A ó san ẹ̀jẹ́ wa fún ọ.+
2 Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, ọ̀dọ̀ rẹ ni onírúurú èèyàn* yóò wá.+
3 Àwọn àṣìṣe mi ti bò mí mọ́lẹ̀,+Àmọ́, o dárí àwọn ìṣìnà wa jì wá.+
4 Aláyọ̀ ni ẹni tí o yàn, tí o sì mú wá sọ́dọ̀ rẹKí ó lè máa gbé inú àwọn àgbàlá rẹ.+
Àwọn ohun rere inú ilé rẹ yóò tẹ́ wa lọ́rùn,+Ìyẹn àwọn ohun inú tẹ́ńpìlì mímọ́* rẹ.+
5 Wàá fi àwọn iṣẹ́ òdodo tó jẹ́ àgbàyanu dá wa lóhùn,+Ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà wa;Ìwọ ni Ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo ayé+Àti ti àwọn tó jìnnà réré lórí òkun.
6 O* fìdí àwọn òkè múlẹ̀ ṣinṣin nípasẹ̀ agbára rẹ;O* gbé agbára ńlá wọ̀ bí aṣọ.+
7 O* mú kí àwọn òkun tó ń ru gùdù rọlẹ̀+Pẹ̀lú ariwo ìgbì wọn àti rúkèrúdò àwọn orílẹ̀-èdè.+
8 Àwọn iṣẹ́ àmì rẹ yóò mú kí ẹ̀rù rẹ ba àwọn tó ń gbé ibi tó jìnnà;+Wàá mú kí àwọn tó wà ní ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn kígbe ayọ̀.
9 Ò ń bójú tó ayé,O mú kí ó ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èso,* kí ilẹ̀ rẹ̀ sì lọ́ràá dáadáa.+
Omi kún inú odò Ọlọ́run;O pèsè oúnjẹ* fún wọn,+Nítorí bí o ṣe ṣètò ayé nìyẹn.
10 O fi omi rin àwọn poro* rẹ̀, o sì mú kí ilẹ̀ rẹ̀ tí a tú* tẹ́jú;O fi ọ̀wààrà òjò mú un dẹ̀; o mú kí ọ̀gbìn rẹ̀ dàgbà.+
11 O fi oore rẹ dé ọdún ládé;Àwọn ohun rere kún ojú ọ̀nà rẹ rẹpẹtẹ.*+
12 Àwọn ibi ìjẹko tó wà ní aginjù kún,*+Àwọn òkè kéékèèké gbé ìdùnnú wọ̀ bí aṣọ.+
13 Àwọn agbo ẹran bo ibi ìjẹko,Ọkà sì bo àwọn àfonífojì.*+
Wọ́n ń kígbe ìṣẹ́gun, bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ń kọrin.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “gbogbo ẹlẹ́ran ara.”
^ Tàbí “ibi mímọ́.”
^ Ní Héb., “Ó.”
^ Ní Héb., “Ó.”
^ Ní Héb., “Ó.”
^ Ní Héb., “kí ó kún àkúnwọ́sílẹ̀.”
^ Ní Héb., “ọkà.”
^ Tàbí “ebè rẹ̀ tí a kọ.”
^ Ìyẹn, àárín ebè.
^ Ní Héb., “Ọ̀rá ń kán tótó ní ojú ọ̀nà rẹ.”
^ Ní Héb., “ń kán tótó.”
^ Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

