Sáàmù 132:1-18

  • Ó yan Dáfídì àti Síónì

    • “Má ṣe kọ ẹni àmì òróró rẹ sílẹ̀” (10)

    • Ó gbé ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà Síónì (16)

Orin Ìgòkè. 132  Jèhófà, jọ̀wọ́ rántí DáfídìÀti gbogbo ìyà tó jẹ;+  Bó ṣe búra fún Jèhófà,Bó ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Alágbára Jékọ́bù pé:+  “Mi ò ní wọnú àgọ́ mi, àní ilé mi.+ Mi ò ní dùbúlẹ̀ lórí àga tìmùtìmù mi, àní ibùsùn mi;  Mi ò ní jẹ́ kí oorun kun ojú mi,Mi ò sì ní jẹ́ kí ìpéǹpéjú mi tòògbé  Títí màá fi rí àyè kan fún Jèhófà,Ibùgbé tó dáa* fún Alágbára Jékọ́bù.”+  Wò ó! A gbọ́ nípa rẹ̀ ní Éfúrátà;+A rí i nínú igbó kìjikìji.+  Ẹ jẹ́ ká wá sínú ibùgbé rẹ̀;*+Ká forí balẹ̀ níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.+  Dìde, Jèhófà, wá sí ibi ìsinmi rẹ,+Ìwọ àti Àpótí agbára rẹ.+  Kí àwọn àlùfáà rẹ gbé òdodo wọ̀,Kí àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ sì máa kígbe ayọ̀. 10  Nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ,Má ṣe kọ ẹni àmì òróró rẹ sílẹ̀.*+ 11  Jèhófà ti búra fún Dáfídì,Ó dájú pé kò ní ṣàìmú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ pé: “Ọ̀kan lára ọmọ* rẹNi màá gbé gorí ìtẹ́ rẹ.+ 12  Tí àwọn ọmọ rẹ bá pa májẹ̀mú mi mọ́Àti àwọn ìránnilétí mi tí mo kọ́ wọn,+Àwọn ọmọ tiwọn náàYóò jókòó sórí ìtẹ́ rẹ títí láé.”+ 13  Nítorí Jèhófà ti yan Síónì;+Ó fẹ́ kó jẹ́ ibùgbé rẹ̀, ó ní:+ 14  “Ibi ìsinmi mi títí láé nìyí;Ibí ni màá máa gbé,+ nítorí ohun tí mo fẹ́ nìyẹn. 15  Màá fi ọ̀pọ̀ oúnjẹ kún ibẹ̀;Màá fi oúnjẹ tẹ́ àwọn aláìní ibẹ̀ lọ́rùn.+ 16  Màá gbé ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ̀,+Àwọn adúróṣinṣin rẹ̀ yóò sì kígbe ayọ̀.+ 17  Màá mú kí agbára Dáfídì pọ̀ sí i* níbẹ̀. Mo ti ṣètò fìtílà fún ẹni àmì òróró mi.+ 18  Màá gbé ìtìjú wọ àwọn ọ̀tá rẹ̀,Àmọ́ adé* orí rẹ̀ yóò máa gbilẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Àgọ́ ìjọsìn títóbi.”
Tàbí “àgọ́ ìjọsìn rẹ̀ títóbi.”
Ní Héb., “yí ojú ẹni àmì òróró rẹ pa dà.”
Ní Héb., “èso ilé ọmọ.”
Ní Héb., “kí ìwo Dáfídì yọ.”
Tàbí “dáyádémà.”