Sáàmù 84:1-12

  • Àárò àgọ́ ìjọsìn títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run ń sọ mí

    • Ó ń wu ọmọ Léfì kan pé kó dà bí ẹyẹ (3)

    • “Ọjọ́ kan nínú àwọn àgbàlá rẹ” (10)

    • “Ọlọ́run jẹ́ oòrùn àti apata” (11)

Fún olùdarí; lórí Gítítì.* Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Orin. 84  Àgọ́ ìjọsìn rẹ títóbi lọ́lá mà dára o,*+Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun!   Àárò ń sọ mí,*Àní, àárẹ̀ ti mú mi bó ṣe ń wù míLáti wá sí àwọn àgbàlá Jèhófà.+ Gbogbo ọkàn àti gbogbo ara mi ni mo fi ń kígbe ayọ̀ sí Ọlọ́run alààyè.   Kódà ẹyẹ rí ilé síbẹ̀,Alápàáǹdẹ̀dẹ̀ sì rí ìtẹ́ fún ara rẹ̀,Ibẹ̀ ló ti ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀Nítòsí pẹpẹ rẹ títóbi lọ́lá, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,Ọba mi àti Ọlọ́run mi!   Aláyọ̀ ni àwọn tó ń gbé inú ilé rẹ!+ Wọ́n ń yìn ọ́ nígbà gbogbo.+ (Sélà)   Aláyọ̀ ni àwọn tó fi ọ́ ṣe agbára wọn,+Àwọn tí ọkàn wọn wà ní ọ̀nà tó lọ sí ilé rẹ.   Nígbà tí wọ́n gba Àfonífojì Bákà* kọjá,Wọ́n sọ ibẹ̀ di ibi ìsun omi;Òjò àkọ́rọ̀ sì fi ìbùkún rin ín.*   Wọ́n á máa ti inú agbára bọ́ sínú agbára;+Kálukú wọn ń wá síwájú Ọlọ́run ní Síónì.   Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, gbọ́ àdúrà mi;Fetí sílẹ̀, ìwọ Ọlọ́run Jékọ́bù. (Sélà)   Kíyè sí i, ìwọ apata+ wa àti Ọlọ́run wa,*Wo ojú ẹni àmì òróró rẹ.+ 10  Nítorí ọjọ́ kan nínú àwọn àgbàlá rẹ sàn ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ níbikíbi!+ Mo yàn láti máa dúró níbi àbáwọlé ilé Ọlọ́run miDípò kí n máa gbé inú àgọ́ àwọn èèyàn burúkú. 11  Nítorí Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ oòrùn+ àti apata;+Ó ń ṣojú rere síni, ó sì ń fúnni ní ògo. Jèhófà kò ní fawọ́ ohun rere sẹ́yìnLọ́dọ̀ àwọn tó ń rìn nínú ìwà títọ́.+ 12  Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,Aláyọ̀ ni ẹni tó gbẹ́kẹ̀ lé ọ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Mo mà fẹ́ràn àgọ́ ìjọsìn rẹ títóbi lọ́lá o.”
Tàbí “Ọkàn mi ń ṣàárò.”
Tàbí “àfonífojì àwọn igi bákà.”
Tàbí kó jẹ́, “Olùkọ́ sì fi ìbùkún bo ara rẹ̀ bí aṣọ.”
Tàbí kó jẹ́, “Ìwọ Ọlọ́run, wo apata wa.”