Sáàmù 131:1-3
-
Mo ní ìtẹ́lọ́rùn bí ọmọ tí a gba ọmú lẹ́nu rẹ̀
-
Mi ò lé nǹkan ńláńlá (1)
-
Orin Ìgòkè. Ti Dáfídì.
131 Jèhófà, mi* ò gbéra ga,Bẹ́ẹ̀ ni ojú mi ò ga;+Bẹ́ẹ̀ ni mi ò máa lé nǹkan ńláńlá,+Tàbí àwọn nǹkan tó kọjá agbára mi.
2 Àmọ́, mo ti tu ọkàn* mi lára, mo sì ti mú kó pa rọ́rọ́ +Bí ọmọ tí a ti gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, tó wà lọ́dọ̀ ìyá rẹ̀;Mo* ní ìtẹ́lọ́rùn bí ọmọ tí a ti gba ọmú lẹ́nu rẹ̀.
3 Kí Ísírẹ́lì dúró de Jèhófà+Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.

