Sáàmù 88:1-18
Orin. Orin àwọn ọmọ Kórà.+ Sí olùdarí; lọ́nà ti Máhálátì,* kí a kọ ọ́ ní àkọgbà. Másíkílì* ti Hémánì+ tó jẹ́ Ẹ́síráhì.
88 Jèhófà, Ọlọ́run ìgbàlà mi,+Mò ń ké ní ọ̀sán,Mo sì ń wá síwájú rẹ ní òru.+
2 Jẹ́ kí àdúrà mi wá síwájú rẹ,+Fetí sí* igbe mi fún ìrànlọ́wọ́.+
3 Nítorí pé wàhálà ti kún ọkàn* mi,+Ẹ̀mí mi sì ti dé ẹnu Isà Òkú.*+
4 Wọ́n ti kà mí mọ́ àwọn tó ń lọ sínú kòtò;*+Mo ti di ẹni tí kò lè ṣe nǹkan kan,*+
5 Tí wọ́n fi sílẹ̀ láàárín àwọn òkú,Bí ẹni tí wọ́n pa, tó dùbúlẹ̀ sínú sàréè,Ẹni tí o kò rántí mọ́,Tí kò sì sí lábẹ́ àbójútó* rẹ mọ́.
6 O ti fi mí sínú kòtò tó jìn jù lọ,Ní ibi tó ṣókùnkùn, nínú ọ̀gbun ńlá tí kò nísàlẹ̀.
7 Ìrunú rẹ pọ̀ lórí mi,+O sì fi ìgbì rẹ tó ń pariwo bò mí mọ́lẹ̀. (Sélà)
8 O ti lé àwọn ojúlùmọ̀ mi jìnnà réré sí mi;+O ti sọ mí di ohun ìríra sí wọn.
Mo ti kó sí pańpẹ́, mi ò sì lè jáde.
9 Ojú mi ti di bàìbàì nítorí ìyà tó ń jẹ mí.+
Mo ké pè ọ́, Jèhófà, láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;+Ìwọ ni mo tẹ́wọ́ àdúrà sí.
10 Ṣé àwọn òkú lo máa ṣe iṣẹ́ àgbàyanu hàn?
Ṣé àwọn tí ikú ti pa* lè dìde wá yìn ọ́?+ (Sélà)
11 Ṣé a lè kéde ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ nínú sàréèTàbí òtítọ́ rẹ ní ibi ìparun?*
12 Ṣé a lè mọ àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ nínú òkùnkùnTàbí òdodo rẹ ní ilẹ̀ àwọn ẹni ìgbàgbé?+
13 Síbẹ̀, Jèhófà, mò ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,+Àràárọ̀ ni àdúrà mi ń wá síwájú rẹ.+
14 Jèhófà, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí* sílẹ̀?+
Kí ló dé tí o fi gbé ojú rẹ pa mọ́ fún mi?+
15 Láti ìgbà èwe miNi ìyà ti ń jẹ mí, mo sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú;+Àwọn àjálù tí o jẹ́ kó dé bá mi ti jẹ́ kí n kú sára.
16 Ìbínú rẹ tó ń jó bí iná bò mí mọ́lẹ̀;+Jìnnìjìnnì láti ọ̀dọ̀ rẹ ti pa mí tán.
17 Wọ́n yí mi ká bí omi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;Wọ́n gba ibi gbogbo yọ sí mi, wọ́n sì ká mi mọ́.*
18 O ti lé àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ mi jìnnà réré sí mi;+Òkùnkùn ti di alábàákẹ́gbẹ́ mi.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “Bẹ̀rẹ̀ kí o sì fetí sí.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “Mo dà bí ọkùnrin tí kò lágbára.”
^ Tàbí “sàréè.”
^ Ní Héb., “ọwọ́.”
^ Tàbí “ti sọ di aláìlágbára.”
^ Tàbí “ní Ábádónì.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí kó jẹ́, “lẹ́ẹ̀kan náà.”

