Sáàmù 82:1-8

  • Ọlọ́run ní kí àwọn èèyàn máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́

    • Ọlọ́run ń ṣe ìdájọ́ ní àárín “àwọn ọlọ́run” (1)

    • “Ẹ gbèjà aláìní” (3)

    • “Ọlọ́run ni yín” (6)

Orin Ásáfù.+ 82  Ọlọ́run dúró sí àyè rẹ̀ nínú àpéjọ ọ̀run;*+Ó ń ṣe ìdájọ́ ní àárín àwọn ọlọ́run*+ pé:   “Títí dìgbà wo ni ẹ ó máa fi àìṣòdodo dá ẹjọ́,+Tí ẹ ó sì máa ṣe ojúsàájú àwọn ẹni burúkú?+ (Sélà)   Ẹ gbèjà* aláìní àti ọmọ aláìníbaba.+ Ẹ dá ẹjọ́ ẹni tí ìyà ń jẹ àti òtòṣì bó ṣe tọ́.+   Ẹ gba aláìní àti tálákà sílẹ̀;Ẹ gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú.”   Wọn ò mọ̀, kò sì yé wọn;+Wọ́n ń rìn kiri nínú òkùnkùn;Gbogbo ìpìlẹ̀ ayé ń mì tìtì.+   “Mo sọ pé, ‘ọlọ́run* ni yín,+Gbogbo yín jẹ́ ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ.   Àmọ́, ẹ̀yin yóò kú bí àwọn èèyàn ṣe ń kú;+Ẹ ó sì ṣubú bí àwọn olórí ṣe ń ṣubú!’”+   Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé,+Nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè jẹ́ tìrẹ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àpéjọ Olú Ọ̀run.”
Tàbí “àwọn ẹni bí Ọlọ́run.”
Tàbí “dá ẹjọ́.”
Tàbí “ẹni bí Ọlọ́run.”