Sáàmù 93:1-5

  • Ìṣàkóso Jèhófà tóbi

    • “Jèhófà ti di Ọba!” (1)

    • “Àwọn ìránnilétí rẹ ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé” (5)

93  Jèhófà ti di Ọba!+ Ó gbé ọlá ńlá wọ̀ bí aṣọ;Jèhófà gbé agbára wọ̀;Ó fi di ara rẹ̀ bí àmùrè. Ayé* fìdí múlẹ̀ gbọn-in;Kò ṣeé ṣí nípò.*   Tipẹ́tipẹ́ ni ìtẹ́ rẹ ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in;+O ti wà láti ayébáyé.+   Àwọn odò ru sókè, Jèhófà,Àwọn odò ru sókè, wọ́n sì pariwo;Àwọn odò ń ru sókè, wọ́n ń ru gùdù.   Jèhófà jẹ́ ọlọ́lá ńlá ní ibi gíga,+Lórí ìró omi púpọ̀,Agbára rẹ̀ ju ti ìgbì òkun tó ń ru gùdù lọ.+   Àwọn ìránnilétí rẹ ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá.+ Jèhófà, ìjẹ́mímọ́ ni ọ̀ṣọ́* ilé rẹ+ títí láé.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Ilẹ̀ tó ń méso jáde.”
Tàbí “Kò lè ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”
Tàbí “ìjẹ́mímọ́ yẹ.”