Sáàmù 85:1-13

  • Àdúrà ìmúbọ̀sípò

    • Ọlọ́run máa sọ̀rọ̀ àlàáfíà fún àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ (8)

    • Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ pàdé (10)

Fún olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Orin. 85  Jèhófà, o ti ṣojú rere sí ilẹ̀ rẹ;+O mú àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú+ lára Jékọ́bù pa dà wá.   O ti gbójú fo àṣìṣe àwọn èèyàn rẹ;O dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n.*+ (Sélà)   O fawọ́ gbogbo ìbínú rẹ tó ń jó bí iná sẹ́yìn;O yí pa dà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ.+   Mú wa bọ̀ sípò,* Ọlọ́run ìgbàlà wa,Kí o má sì bínú sí wa mọ́.+   Ṣé títí láé ni wàá máa bínú sí wa ni?+ Ṣé wàá jẹ́ kí ìbínú rẹ máa lọ láti ìran dé ìran ni?   Ṣé o ò ní mú wa sọ jí ni,Kí àwọn èèyàn rẹ lè máa yọ̀ nínú rẹ?+   Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa, Jèhófà,+Kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ.   Màá fetí sí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ sọ,Nítorí ó máa sọ̀rọ̀ àlàáfíà fún àwọn èèyàn rẹ̀,+ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀,Àmọ́ kí wọ́n má ṣe pa dà máa dá ara wọn lójú jù.+   Ó dájú pé ìgbàlà rẹ̀ wà nítòsí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀,+Kí ògo rẹ̀ lè máa gbé ní ilẹ̀ wa. 10  Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ yóò pàdé ara wọn;Òdodo àti àlàáfíà yóò fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu.+ 11  Òtítọ́ yóò rú jáde látinú ilẹ̀,Òdodo yóò sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run.+ 12  Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà yóò pèsè ohun rere,*+Ilẹ̀ wa yóò sì máa mú èso jáde.+ 13  Òdodo yóò máa rìn níwájú rẹ̀,+Yóò sì la ọ̀nà fún ìṣísẹ̀ rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “O bo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
Tàbí “Kó wa pa dà.”
Tàbí “aásìkí.”