Sáàmù 60:1-12
Sí olùdarí; kí a yí i sí “Òdòdó Lílì Ìránnilétí.” Míkítámù.* Ti Dáfídì. Fún kíkọ́ni. Nígbà tó bá Aramu-náháráímù àti Aramu-Sóbà jà, tí Jóábù sì pa dà lọ pa 12,000 àwọn ọmọ Édómù ní Àfonífojì Iyọ̀.+
60 Ọlọ́run, o ti pa wá tì; o ti ya ààbò wa lulẹ̀.+
O bínú sí wa; àmọ́ ní báyìí, gbà wá pa dà!
2 O mú kí ilẹ̀ ayé mì tìtì; o mú kí ó lanu.
Dí àwọn àlàfo rẹ̀, torí ó ti ń wó.
3 O mú kí ìyà jẹ àwọn èèyàn rẹ.
O mú kí a mu wáìnì tó ń mú wa ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+
4 Fún* àwọn tó bẹ̀rù rẹ ní àmìKí wọ́n lè sá, kí wọ́n sì yẹ ọfà.* (Sélà)
5 Kí a lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ sílẹ̀,Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbà wá sílẹ̀, kí o sì dá wa lóhùn.+
6 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ nínú ìjẹ́mímọ́* rẹ̀ pé:
“Màá yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun, màá fi Ṣékémù ṣe ogún fún àwọn èèyàn mi,+Màá sì díwọ̀n Àfonífojì* Súkótù fún ẹni tí mo bá fẹ́.+
7 Gílíádì jẹ́ tèmi, bí Mánásè ṣe jẹ́ tèmi,+Éfúrémù sì ni akoto* orí mi;Júdà ni ọ̀pá àṣẹ mi.+
8 Móábù ni bàsíà tí mo fi ń wẹ ẹsẹ̀.+
Orí Édómù ni màá ju bàtà mi sí.+
Màá kígbe ìṣẹ́gun lórí Filísíà.”+
9 Ta ló máa mú mi wá sí ìlú tí a dó tì?*
Ta ló máa mú mi lọ sí Édómù?+
10 Ìwọ Ọlọ́run tí o ti kọ̀ wá sílẹ̀ náà ni,Ìwọ Ọlọ́run wa, tí o kò bá àwọn ọmọ ogun wa jáde mọ́.+
11 Ràn wá lọ́wọ́ nínú wàhálà wa,Nítorí asán ni ìgbàlà látọwọ́ èèyàn.+
12 Ọlọ́run ló máa fún wa lágbára,+Yóò sì tẹ àwọn ọ̀tá wa rẹ́.+

