Sáàmù 77:1-20
Sí olùdarí; lórí Jédútúnì.*+ Ti Ásáfù. Orin.
77 Màá fi ohùn mi ké pe Ọlọ́run;Màá ké pe Ọlọ́run, yóò sì gbọ́ mi.+
2 Ní ọjọ́ wàhálà mi, mo wá Jèhófà.+
Ní òru, mi ò dẹ́kun* títẹ́wọ́ àdúrà sí i.
Síbẹ̀, mi* ò gba ìtùnú.
3 Nígbà tí mo rántí Ọlọ́run, mo kérora;+Ìdààmú bá mi, mi ò sì lágbára mọ́.*+ (Sélà)
4 Ìwọ mú kí ojú mi là sílẹ̀;Wàhálà bá mi, mi ò sì lè sọ̀rọ̀.
5 Mo rántí ìgbà àtijọ́,+Àwọn ọdún tó ti kọjá tipẹ́tipẹ́.
6 Ní òru, mo rántí orin mi;*+Mo ṣàṣàrò nínú ọkàn mi;+Mo* fara balẹ̀ ṣèwádìí.
7 Ṣé títí láé ni Jèhófà máa ta wá nù ni?+
Ṣé kò ní ṣojú rere sí wa mọ́ láé ni?+
8 Ṣé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ti dáwọ́ dúró títí ayé ni?
Ṣé ìlérí rẹ̀ máa já sí asán fún gbogbo ìran ni?
9 Ṣé Ọlọ́run ti gbàgbé láti ṣojú rere ni,+Àbí, ṣé ìbínú rẹ̀ ti dínà àánú rẹ̀ ni? (Sélà)
10 Ṣé ó yẹ kí n máa sọ ní gbogbo ìgbà pé: “Ohun tó ń kó ìdààmú bá* mi ni pé:+
Ẹni Gíga Jù Lọ ti kọ ẹ̀yìn* sí wa”?
11 Màá rántí àwọn iṣẹ́ Jáà;Màá rántí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tí o ti ṣe tipẹ́tipẹ́.
12 Màá ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ,Màá sì ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ohun tí o ṣe.+
13 Ọlọ́run, àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ mímọ́.
Ìwọ Ọlọ́run, ọlọ́run wo ló tóbi bí rẹ?+
14 Ìwọ ni Ọlọ́run tòótọ́, tó ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu.+
O ti fi agbára rẹ han àwọn èèyàn.+
15 O fi agbára* rẹ gba àwọn èèyàn rẹ sílẹ̀,*+Àwọn ọmọ Jékọ́bù àti ti Jósẹ́fù. (Sélà)
16 Omi rí ọ, ìwọ Ọlọ́run;Omi rí ọ, ó sì dà rú.+
Ibú omi ru gùdù.
17 Àwọsánmà da omi sílẹ̀.
Ojú ọ̀run tó ṣú dẹ̀dẹ̀ sán ààrá,Àwọn ọfà rẹ sì ń fò síbí sọ́hùn-ún.+
18 Ìró ààrá rẹ+ dà bí ìró àgbá kẹ̀kẹ́ ẹṣin;Mànàmáná tó ń kọ mú kí ilẹ̀ ayé tí à ń gbé* mọ́lẹ̀;+Ayé mì tìtì, ó sì mì jìgìjìgì.+
19 Ọ̀nà rẹ gba inú òkun kọjá,+Ipa ọ̀nà rẹ sì gba inú omi púpọ̀ kọjá;Àmọ́ a kò lè rí ipa ẹsẹ̀ rẹ.
20 O darí àwọn èèyàn rẹ bí agbo ẹran,+Lábẹ́ àbójútó* Mósè àti Áárónì.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ní Héb., “ọwọ́ mi ò kú tipiri.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Ní Héb., “ẹ̀mí mi dá kú.”
^ Tàbí “orin tí mo fi ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín kọ.”
^ Ní Héb., “Ẹ̀mí mi.”
^ Ní Héb., “yí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ pa dà.”
^ Tàbí “tó ń gún.”
^ Ní Héb., “apá.”
^ Ní Héb., “ra àwọn èèyàn rẹ pa dà.”
^ Tàbí “ilẹ̀ tó ń méso jáde.”
^ Ní Héb., “Nípa ọwọ́.”

