Sáàmù 129:1-8

  • Wọ́n gbógun tì í, àmọ́ wọn ò ṣẹ́gun

    • Ojú ti àwọn tó kórìíra Síónì (5)

Orin Ìgòkè. 129  “Láti ìgbà èwe mi ni wọ́n ti ń gbógun tì mí”+—Kí Ísírẹ́lì sọ pé—  “Láti ìgbà èwe mi ni wọ́n ti ń gbógun tì mí;+Àmọ́, wọn kò ṣẹ́gun mi.+  Àwọn tó ń túlẹ̀ ti túlẹ̀ kọjá lórí ẹ̀yìn mi;+Wọ́n ti mú kí àwọn poro* wọn gùn.”  Àmọ́ olódodo ni Jèhófà;+Ó ti gé okùn àwọn ẹni burúkú.+  Ojú á tì wọ́n, wọ́n á sì sá pa dà nínú ìtìjú,Gbogbo àwọn tó kórìíra Síónì.+  Wọ́n á dà bíi koríko orí òrùléTó ti rọ kí a tó fà á tu,  Tí kò lè kún ọwọ́ ẹni tó ń kórè,Tàbí apá ẹni tó ń kó ìtí jọ.  Àwọn tó ń kọjá lọ kò ní sọ pé: “Kí ìbùkún Jèhófà wà lórí yín;A súre fún yín ní orúkọ Jèhófà.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìyẹn, àárín ebè.