Sáàmù 101:1-8

  • Alákòóso tó ń hu ìwà títọ́

    • ‘Mi ò ní gba ìgbéraga láyè’ (5)

    • “Màá bojú wo àwọn olóòótọ́” (6)

Ti Dáfídì. Orin. 101  Màá kọrin nípa ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti ìdájọ́ òdodo. Jèhófà, ìwọ ni màá kọ orin ìyìn sí.*  2  Màá hu ìwà ọgbọ́n àti ìwà àìlábààwọ́n.* Ìgbà wo lo máa wá bá mi? Màá fi òtítọ́ ọkàn+ rìn nínú ilé mi.  3  Mi ò ní gbé ohun tí kò ní láárí* sí iwájú mi. Mo kórìíra iṣẹ́ àwọn tó ń yà kúrò nínú ohun tí ó tọ́;+Mi ò ní bá wọn da nǹkan kan pọ̀.*  4  Ọkàn ẹ̀tàn jìnnà sí mi;Mi ò ní gba* ohun búburú kankan.  5  Ẹnikẹ́ni tó bá ń ba ọmọnìkejì rẹ̀ jẹ́ ní ìkọ̀kọ̀,+Màá pa á lẹ́nu mọ́.* Ẹnikẹ́ni tó bá ní ojú ìgbéraga àti ọkàn gíga,Mi ò ní gbà á láyè.  6  Màá bojú wo àwọn olóòótọ́ ayé,Kí wọ́n lè máa bá mi gbé. Ẹni tó ń rìn láìní àbààwọ́n* yóò máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi.  7  Kò sí ẹlẹ́tàn kankan tó máa gbé inú ilé mi,Kò sì sí òpùrọ́ kankan tó máa dúró níwájú* mi.  8  Ní àràárọ̀, màá pa gbogbo àwọn ẹni burúkú ayé lẹ́nu mọ́,*Láti mú gbogbo àwọn aṣebi kúrò ní ìlú Jèhófà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Tàbí “kọrin sí.”
^ Tàbí “ìwà títọ́.”
^ Tàbí “ohun tí kò wúlò.”
^ Tàbí “Ìwà wọn kò mọ́ mi lára.”
^ Ní Héb., “mọ.”
^ Tàbí “mú un kúrò.”
^ Tàbí “nínú ìwà títọ́.”
^ Tàbí “lọ́dọ̀.”
^ Tàbí “mú gbogbo àwọn ẹni burúkú ayé kúrò.”