Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌBÉÈRÈ 3

Ta Ló Kọ Bíbélì?

“Mósè . . . kọ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà sílẹ̀.”

Ẹ́kísódù 24:4

“Dáníẹ́lì lá àlá, ó sì rí àwọn ìran nígbà tó dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn rẹ̀. Ó wá kọ àlá náà sílẹ̀; ó kọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”

Dáníẹ́lì 7:1

“Nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ gbọ́ lọ́dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ èèyàn, àmọ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ lóòótọ́, bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”

1 Tẹsalóníkà 2:13

“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì wúlò fún kíkọ́ni.”

2 Tímótì 3:16

“A ò fìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípasẹ̀ ìfẹ́ èèyàn, àmọ́ àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí wọn.”

2 Pétérù 1:21