Sáàmù 17:1-15
Àdúrà Dáfídì.
17 Jèhófà, gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ìdájọ́ òdodo;Fiyè sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́;Fetí sí àdúrà tí mo gbà láìṣẹ̀tàn.+
2 Kí o ṣe ìpinnu tí ó tọ́ nítorí mi;+Kí ojú rẹ rí ohun tí ó tọ́.
3 O ti ṣàyẹ̀wò ọkàn mi, o ti bẹ̀ mí wò ní òru;+O ti yọ́ mi mọ́;+Wàá rí i pé mi ò ní èrò ibi kankan lọ́kàn,Ẹnu mi kò sì dẹ́ṣẹ̀.
4 Ohunkóhun tí àwọn èèyàn ì báà máa ṣe,Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, mo yẹra fún ọ̀nà àwọn ọlọ́ṣà.+
5 Má ṣe jẹ́ kí ìṣísẹ̀ mi kúrò ní ọ̀nà rẹKí n má bàa kọsẹ̀.+
6 Ọlọ́run, mò ń ké pè ọ́, torí mo mọ̀ pé wàá dá mi lóhùn.+
Tẹ́tí sí mi.* Gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.+
7 Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn lọ́nà àgbàyanu,+Ìwọ Olùgbàlà àwọn tó ń wá ààbò ní ọwọ́ ọ̀tún rẹKí ọwọ́ àwọn tó ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọ má bàa tẹ̀ wọ́n.
8 Dáàbò bò mí bí ọmọlójú rẹ;+Fi mí pa mọ́ sábẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ.+
9 Dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú tó ń gbéjà kò mí.
Lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá alénimádẹ̀yìn* tí wọ́n yí mi ká.+
10 Wọ́n ti yigbì;*Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ìgbéraga;
11 Ní báyìí, wọ́n ti ká wa mọ́;+Wọ́n ń wá ọ̀nà tí wọ́n á fi gbé wa ṣubú.*
12 Ó dà bíi kìnnìún tó fẹ́ fa ẹran ya,Bí ọmọ kìnnìún tó lúgọ síbi ìkọ̀kọ̀.
13 Dìde Jèhófà, kí o kò ó lójú+ kí o sì mú un balẹ̀;Fi idà rẹ gbà mí* lọ́wọ́ ẹni burúkú;
14 Jèhófà, fi ọwọ́ rẹ gbà mí sílẹ̀,Lọ́wọ́ àwọn èèyàn ayé* yìí, àwọn tí ìpín wọn jẹ́ ti ayé yìí,+Àwọn tí o fún ní àwọn ohun rere tí o ti pèsè,+Àwọn tí wọ́n fi ogún sílẹ̀ fún ọmọ púpọ̀.
15 Àmọ́ ní tèmi, màá rí ojú rẹ nínú òdodo;Ó tẹ́ mi lọ́rùn láti máa jí rí ọ.*+

