Sáàmù 59:1-17

  • Ọlọ́run jẹ́ apata àti ibi ààbò

    • ‘Má ṣe ṣàánú àwọn ọ̀dàlẹ̀’ (5)

    • “Màá kọrin nípa okun rẹ” (16)

Sí olùdarí; kí a yí i sí “Má Ṣe Pa Á Run.” Ti Dáfídì. Míkítámù.* Nígbà tí Sọ́ọ̀lù rán àwọn èèyàn pé kí wọ́n lọ máa ṣọ́ ilé Dáfídì* kí ó lè pa á.+ 59  Ọlọ́run mi, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi;+Dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn tó ń dìde sí mi.+   Gbà mí lọ́wọ́ àwọn tó ń hùwà burúkú,Kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá.*   Wò ó! wọ́n lúgọ dè mí;*+Àwọn alágbára gbéjà kò míÀmọ́ Jèhófà, kì í ṣe torí pé mo ṣọ̀tẹ̀ tàbí pé mo dẹ́ṣẹ̀.+   Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò ṣe ohun tí kò dáa, wọ́n sáré múra sílẹ̀ láti bá mi jà. Dìde nígbà tí mo bá pè, kí o sì wò mí.   Nítorí ìwọ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ Jí láti yí àfiyèsí rẹ sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. Má ṣe ṣàánú ẹnikẹ́ni tó jẹ́ ọ̀dàlẹ̀ abatẹnijẹ́.+ (Sélà)   Wọ́n ń wá ní ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́;+ Wọ́n ń kùn* bí ajá,+ wọ́n sì ń dọdẹ kiri ìlú.+   Wo ohun tó ń tú* jáde lẹ́nu wọn;Ètè wọn dà bí idà,+Wọ́n ń sọ pé: “Ta ló ń gbọ́ wa?”+   Àmọ́ ìwọ, Jèhófà, yóò fi wọ́n rẹ́rìn-ín;+Wàá fi gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣẹ̀sín.+   Ìwọ Okun mi, ìwọ ni èmi yóò máa wò;+Nítorí Ọlọ́run ni ibi ààbò mi.*+ 10  Ọlọ́run tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi yóò ràn mí lọ́wọ́;+Ọlọ́run yóò mú kí n rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi.+ 11  Má pa wọ́n, kí àwọn èèyàn mi má bàa gbàgbé. Fi agbára rẹ mú kí wọ́n máa rìn gbéregbère;Mú kí wọ́n ṣubú, ìwọ Jèhófà, apata wa.+ 12  Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó wà lẹ́nu wọn àti ọ̀rọ̀ ètè wọn,Kí ìgbéraga wọn dẹkùn mú wọn,+Nítorí ègún àti ẹ̀tàn tí wọ́n ń sọ lẹ́nu. 13  Yanjú wọn nínú ìbínú rẹ;+Yanjú wọn, kí wọ́n má bàa sí mọ́;Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run ń ṣàkóso ní Jékọ́bù títí dé gbogbo ìkángun ayé.+ (Sélà) 14  Jẹ́ kí wọ́n pa dà wá ní ìrọ̀lẹ́;Jẹ́ kí wọ́n máa kùn* bí ajá, kí wọ́n sì máa dọdẹ kiri ìlú.+ 15  Jẹ́ kí wọ́n máa wá ohun tí wọ́n á jẹ kiri;+Má ṣe jẹ́ kí wọ́n yó tàbí kí wọ́n rí ibi sùn. 16  Àmọ́ ní tèmi, màá kọrin nípa okun rẹ;+Ní àárọ̀, màá fi ìdùnnú sọ nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Nítorí ìwọ ni ibi ààbò mi+Àti ibi tí mo lè sá sí ní ọjọ́ wàhálà mi.+ 17  Ìwọ Okun mi, ìwọ ni màá fi orin yìn,*+Nítorí Ọlọ́run ni ibi ààbò mi, Ọlọ́run tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “ilé náà.”
Tàbí “àwọn tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ.”
Tàbí “de ọkàn mi.”
Tàbí “gbó.”
Tàbí “ru.”
Tàbí “ibi gíga mi tó láàbò.”
Tàbí “gbó.”
Tàbí “kọrin sí.”