Sáàmù 63:1-11
Orin Dáfídì, nígbà tó wà ní aginjù Júdà.+
63 Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi, mò ń wá ọ.+
Ọkàn mi ń fà sí ọ.*+
Àárẹ̀ ti mú mi* nítorí bó ṣe ń wù mí láti rí ọNí ilẹ̀ tó gbẹ táútáú, níbi tí kò sí omi.+
2 Torí náà, mo wò ọ́ ní ibi mímọ́;Mo rí agbára rẹ àti ògo rẹ.+
3 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ sàn ju ìyè,+Ètè mi yóò máa yìn ọ́ lógo.+
4 Torí náà, èmi yóò máa yìn ọ́ ní gbogbo ọjọ́ ayé mi;Èmi yóò máa gbé ọwọ́ mi sókè ní orúkọ rẹ.
5 Ìpín tó dára jù lọ, tó sì ṣeyebíye jù lọ la fi tẹ́ mi* lọ́rùn,*Torí náà, ẹnu mi yóò yìn ọ́, ètè mi yóò sì kọrin.+
6 Mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi;Mò ń ṣe àṣàrò nípa rẹ nígbà ìṣọ́ òru.+
7 Nítorí ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi,+Mo sì ń kígbe ayọ̀ lábẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ.+
8 Mo* rọ̀ mọ́ ọ;Ọwọ́ ọ̀tún rẹ dì mí mú ṣinṣin.+
9 Àmọ́ àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí mi*Yóò jìn sínú kòtò ikú.
10 A ó fi wọ́n fún idà,Wọ́n á sì di oúnjẹ fún àwọn ajáko.*
11 Àmọ́ ọba yóò máa yọ̀ nínú Ọlọ́run.
Gbogbo ẹni tó ń fi Í búra yóò máa yìn Ín,*Nítorí a ó pa àwọn tó ń parọ́ lẹ́nu mọ́.

