Sáàmù 92:1-15
Orin atunilára. Orin ọjọ́ Sábáàtì.
92 Ó dára láti máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà+Àti láti máa fi orin yin* orúkọ rẹ, ìwọ Ẹni Gíga Jù Lọ,
2 Láti máa kéde ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀+ ní àárọ̀Àti òtítọ́ rẹ ní òru,
3 Pẹ̀lú ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín mẹ́wàá àti gòjé,Nípasẹ̀ háàpù tó ń dún dáadáa.+
4 Jèhófà, ò ń mú inú mi dùn, nítorí àwọn ohun tí ò ń ṣe;Mò ń kígbe ayọ̀ nítorí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
5 Àwọn iṣẹ́ rẹ mà tóbi o, Jèhófà!+
Èrò rẹ jinlẹ̀ gidigidi!+
6 Kò sí aláìnírònú tó lè mọ̀ wọ́n;Kò sì sí òmùgọ̀ tó lè lóye èyí:+
7 Nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá rú jáde bíi koríko*Tí gbogbo àwọn aṣebi sì gbilẹ̀,Kí wọ́n lè pa run títí láé ni.+
8 Àmọ́, ẹni gíga ni ọ́ títí láé, Jèhófà.
9 Wo ìṣubú àwọn ọ̀tá rẹ, Jèhófà,Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ṣe máa ṣègbé;Gbogbo àwọn aṣebi yóò tú ká.+
10 Àmọ́ wàá mú kí agbára mi pọ̀ sí i* bíi ti akọ màlúù igbó;Màá fi òróró dáradára para.+
11 Ojú mi á rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi;+Etí mi á gbọ́ nípa ìṣubú àwọn aṣebi tó ń bá mi jà.
12 Àmọ́ olódodo máa gbilẹ̀ bí igi ọ̀pẹWọ́n á sì tóbi bí igi kédárì ní Lẹ́bánónì.+
13 Ilé Jèhófà ni a gbìn wọ́n sí;Wọ́n ń gbilẹ̀ ní àwọn àgbàlá Ọlọ́run wa.+
14 Kódà nígbà arúgbó* wọn, wọ́n á máa lókun;+Wọ́n á ṣì máa ta kébé,* ara wọn á sì máa dán,+
15 Láti máa kéde pé adúróṣinṣin ni Jèhófà.
Òun ni Àpáta+ mi, ẹni tí kò sí àìṣòdodo nínú rẹ̀.

