Sáàmù 123:1-4
Orin Ìgòkè.
123 Ìwọ ni mo gbé ojú mi sókè sí,+Ìwọ tí o gúnwà ní ọ̀run.
2 Bí ojú àwọn ìránṣẹ́ ṣe ń wo ọwọ́ ọ̀gá wọnÀti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ṣe ń wo ọwọ́ ọ̀gá rẹ̀ obìnrin,Bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Jèhófà Ọlọ́run wa,+Títí á fi ṣojú rere sí wa.+
3 Ṣojú rere sí wa, Jèhófà, ṣojú rere sí wa,Nítorí wọ́n ti kàn wá lábùkù dé góńgó.+
4 Àwọn ajọra-ẹni-lójú ti fi wá ṣẹ̀sín dé góńgó,*Àwọn agbéraga sì ti kàn wá lábùkù gidigidi.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “fi ọkàn wa ṣẹ̀sín kọjá bó ṣe yẹ.”

