Sáàmù 62:1-12

  • Ìgbàlà tòótọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run

    • “Mo dúró jẹ́ẹ́ de Ọlọ́run” (1, 5)

    • ‘Ẹ tú ọkàn yín jáde níwájú Ọlọ́run’ (8)

    • Àwọn èèyàn jẹ́ èémí lásán (9)

    • Má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ (10)

Sí olùdarí; ti Jédútúnì.* Orin Dáfídì. 62  Ní tòótọ́, mo* dúró jẹ́ẹ́ de Ọlọ́run. Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìgbàlà mi ti wá.+   Ní tòótọ́, òun ni àpáta mi àti ìgbàlà mi, ibi ààbò mi;*+Mìmì kan ò ní mì mí débi tí màá ṣubú.+   Ìgbà wo lẹ máa kọ lu ọkùnrin kan dà kí ẹ lè pa á?+ Gbogbo yín léwu bí ògiri tó dagun, ògiri olókùúta tó ti fẹ́ wó.*   Nítorí wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti taari rẹ̀ kúrò ní ipò gíga tó wà;*Wọ́n fẹ́ràn láti máa parọ́. Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre, àmọ́ nínú wọn lọ́hùn-ún, wọ́n ń gégùn-ún.+ (Sélà)   Ní tòótọ́, mo* dúró jẹ́ẹ́ de Ọlọ́run+Nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi ti wá.+   Ní tòótọ́, òun ni àpáta mi àti ìgbàlà mi, ibi ààbò mi;Mìmì kan ò ní mì mí.+   Ọwọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi àti ògo mi wà. Ọlọ́run ni àpáta lílágbára àti ibi ààbò mi.+   Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé e ní gbogbo ìgbà. Ẹ tú ọkàn yín jáde níwájú rẹ̀.+ Ọlọ́run jẹ́ ibi ààbò fún wa.+ (Sélà)   Èémí lásán ni àwọn ọmọ èèyàn,Ẹ̀tàn ni àwọn ọmọ aráyé.+ Tí a bá gbé gbogbo wọn lórí òṣùwọ̀n, wọ́n fúyẹ́ ju èémí lásán.+ 10  Ẹ má rò pé lílọ́ni lọ́wọ́ gbà máa mú kí ẹ ṣàṣeyọrí,Ẹ má sì rò pé olè jíjà máa ṣe yín láǹfààní. Tí ọrọ̀ yín bá ń pọ̀ sí i, ẹ má ṣe gbọ́kàn lé e.+ 11  Ọlọ́run sọ̀rọ̀, mo sì gbọ́ lẹ́ẹ̀mejì: Pé agbára jẹ́ ti Ọlọ́run.+ 12  Bákan náà, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ jẹ́ tìrẹ, Jèhófà,+Nítorí o máa ń san kálukú lẹ́san iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “ibi gíga mi tó láàbò.”
Tàbí kó jẹ́, “Gbogbo yín, bíi pé ó jẹ́ ògiri tó dagun, ògiri olókùúta tó ti fẹ́ wó.”
Tàbí “ipò iyì rẹ̀.”
Tàbí “ìwọ ọkàn mi.”