Sáàmù 105:1-45
105 Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà,+ ẹ ké pe orúkọ rẹ̀,Ẹ jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ àwọn ohun tí ó ṣe!+
2 Ẹ kọrin sí i, ẹ fi orin yìn ín,*Ẹ máa ronú lórí* gbogbo àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀.+
3 Ẹ máa fi orúkọ mímọ́ rẹ̀ yangàn.+Kí ọkàn àwọn tó ń wá Jèhófà máa yọ̀.+
4 Ẹ máa wá Jèhófà+ àti agbára rẹ̀.
Ẹ máa wá ojú rẹ̀* nígbà gbogbo.
5 Ẹ máa rántí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tó ti ṣe,Àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti àwọn ìdájọ́ tó kéde,+
6 Ẹ̀yin ọmọ* Ábúráhámù ìránṣẹ́ rẹ̀,+
Ẹ̀yin ọmọ Jékọ́bù, ẹ̀yin àyànfẹ́ rẹ̀.+
7 Òun ni Jèhófà Ọlọ́run wa.+
Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ kárí ayé.+
8 Ó ń rántí májẹ̀mú rẹ̀ títí láé,+Ìlérí tó ṣe* títí dé ẹgbẹ̀rún ìran,+
9 Májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá+Àti ìbúra rẹ̀ fún Ísákì,+
10 Èyí tó gbé kalẹ̀ bí ìlànà fún Jékọ́bùÀti bíi májẹ̀mú tó wà títí láé fún Ísírẹ́lì,
11 Ó ní, “Màá fún ọ ní ilẹ̀ Kénáánì+Bí ogún tí a pín fún yín.”+
12 Èyí jẹ́ nígbà tí wọ́n kéré níye,+Bẹ́ẹ̀ ni, tí wọ́n kéré níye gan-an, tí wọ́n sì jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ náà.+
13 Wọ́n ń rìn kiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè,
Láti ọ̀dọ̀ ìjọba kan dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn míì.+
14 Kò gbà kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára,+Ṣùgbọ́n nítorí wọn, ó bá àwọn ọba wí,+
15 Ó ní, “Ẹ má fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi,Ẹ má sì ṣe ohun búburú sí àwọn wòlíì mi.”+
16 Ó pe ìyàn wá sórí ilẹ̀ náà;+Ó dí ibi tí búrẹ́dì ń gbà wọlé sọ́dọ̀ wọn.*
17 Ó rán ọkùnrin kan lọ ṣáájú wọn,Jósẹ́fù, ẹni tí wọ́n tà lẹ́rú.+
18 Wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ de ẹsẹ̀ rẹ̀,*+Wọ́n fi irin de ọrùn rẹ̀;*
19 Títí ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi ṣẹ,+Ọ̀rọ̀ Jèhófà ló yọ́ ọ mọ́.
20 Ọba ní kí wọ́n lọ tú u sílẹ̀,+Alákòóso àwọn èèyàn náà dá a sílẹ̀.
21 Ó fi í ṣe ọ̀gá lórí agbo ilé rẹ̀Àti alákòóso lórí gbogbo ohun ìní rẹ̀,+
22 Kó lè lo àṣẹ lórí* àwọn ìjòyè rẹ̀ bó ṣe fẹ́,*Kó sì kọ́ àwọn àgbààgbà rẹ̀ ní ọgbọ́n.+
23 Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì wá sí Íjíbítì,+Jékọ́bù sì di àjèjì ní ilẹ̀ Hámù.
24 Ọlọ́run mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ pọ̀ rẹpẹtẹ;+Ó mú kí wọ́n lágbára ju àwọn ọ̀tá wọn lọ,+
25 Àwọn tó jẹ́ kí ọkàn wọn yí pa dà kí wọ́n lè kórìíra àwọn èèyàn rẹ̀,Kí wọ́n sì dìtẹ̀ mọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+
26 Ó rán Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀+Àti Áárónì,+ ẹni tí ó yàn.
27 Wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ láàárín wọn,Àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ní ilẹ̀ Hámù.+
28 Ó rán òkùnkùn, ilẹ̀ náà sì ṣókùnkùn;+Wọn kò ṣọ̀tẹ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
29 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,Ó sì pa ẹja wọn.+
30 Àwọn àkèré ń gbá yìn-ìn ní ilẹ̀ wọn,+Kódà nínú àwọn yàrá ọba.
31 Ó pàṣẹ pé kí àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ ya wọlé,Kí kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀ sì bo gbogbo ilẹ̀ wọn.+
32 Ó sọ òjò wọn di yìnyín,Ó sì rán mànàmáná* sí ilẹ̀ wọn.+
33 Ó kọ lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn,Ó sì ṣẹ́ àwọn igi tó wà ní ilẹ̀ wọn sí wẹ́wẹ́.
34 Ó ní kí àwọn eéṣú ya wọlé,
Àwọn ọmọ eéṣú tí kò níye.+
35 Wọ́n jẹ gbogbo ewéko ilẹ̀ náà,Wọ́n sì jẹ irè oko wọn.
36 Lẹ́yìn náà, ó pa gbogbo àkọ́bí tó wà ní ilẹ̀ wọn,+Ìbẹ̀rẹ̀ agbára ìbímọ wọn.
37 Ó mú àwọn èèyàn rẹ̀ jáde tàwọn ti fàdákà àti wúrà;+Ìkankan lára àwọn ẹ̀yà rẹ̀ kò sì kọsẹ̀.
38 Íjíbítì yọ̀ nígbà tí wọ́n kúrò,Nítorí ìbẹ̀rù Ísírẹ́lì* ti bò wọ́n.+
39 Ó na àwọsánmà* bo àwọn èèyàn rẹ̀,+Ó sì pèsè iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ ní òru.+
40 Wọ́n béèrè ẹran, ó sì fún wọn ní àparò;+Ó ń fi oúnjẹ láti ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn.+
41 Ó ṣí àpáta, omi sì ṣàn jáde;+Ó ṣàn gba aṣálẹ̀ kọjá bí odò.+
42 Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ tó ṣe fún Ábúráhámù ìránṣẹ́ rẹ̀.+
43 Torí náà, ó mú àwọn èèyàn rẹ̀ jáde tayọ̀tayọ̀,+Ó mú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jáde pẹ̀lú igbe ìdùnnú.
44 Ó fún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè;+Wọ́n jogún ohun tí àwọn míì ti ṣiṣẹ́ kára láti mú jáde,+
45 Kí wọ́n lè máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,+Kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àwọn òfin rẹ̀.
Ẹ yin Jáà!*
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí kó jẹ́, “sọ nípa.”
^ Tàbí “kọ orin fún un.”
^ Tàbí “ibi tó wà.”
^ Tàbí “àtọmọdọ́mọ.” Ní Héb., “èso.”
^ Ní Héb., “ọ̀rọ̀ tó pa láṣẹ.”
^ Ní Héb., “Ó ṣẹ́ gbogbo ọ̀pá búrẹ́dì.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń tọ́jú búrẹ́dì pa mọ́.
^ Ní Héb., “jẹ ẹsẹ̀ rẹ̀ níyà.”
^ Tàbí “Ọkàn rẹ̀ wọnú irin.”
^ Tàbí “bó bá ṣe tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn.”
^ Ní Héb., “Kó lè de.”
^ Tàbí “ọwọ́ iná.”
^ Ní Héb., “wọn.”
^ Tàbí “ìkùukùu.”
^ Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

