Sáàmù 57:1-11

  • Ẹ̀bẹ̀ fún ojú rere

    • Ààbò lábẹ́ ìyẹ́ apá Ọlọ́run (1)

    • Àwọn ọ̀tá kó sínú pańpẹ́ tí àwọn fúnra wọn dẹ (6)

Sí olùdarí; kí a yí i sí “Má Ṣe Pa Á Run.” Ti Dáfídì. Míkítámù.* Nígbà tó sá nítorí Sọ́ọ̀lù, tó sì lọ sínú ihò àpáta.+ 57  Ṣojú rere sí mi, Ọlọ́run, ṣojú rere sí mi,Nítorí ìwọ ni mo* fi ṣe ibi ààbò,+Abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ sì ni mo sá sí títí wàhálà fi kọjá lọ.+   Mo ké pe Ọlọ́run, Ẹni Gíga Jù Lọ,Ọlọ́run tòótọ́, ẹni tó bá mi pa wọ́n rẹ́.   Yóò pèsè ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀run, yóò sì gbà mí là.+ Yóò mú kí ìsapá ẹni tó ń kù gìrì mọ́ mi já sí asán. (Sélà) Ọlọ́run yóò fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ ránṣẹ́.+   Àwọn kìnnìún yí mi* ká;+Àárín àwọn tó fẹ́ fà mí ya ni mo dùbúlẹ̀ sí,Àwọn tí eyín wọn jẹ́ ọ̀kọ̀ àti ọfà,Tí ahọ́n wọn sì jẹ́ idà mímú.+   Kí a gbé ọ ga ju ọ̀run lọ, ìwọ Ọlọ́run;Kí ògo rẹ wà lórí gbogbo ayé.+   Wọ́n ti dẹ àwọ̀n láti fi mú ẹsẹ̀ mi;+Ìdààmú dorí mi* kodò.+ Wọ́n ti gbẹ́ kòtò dè mí,Àmọ́ àwọn fúnra wọn kó sínú rẹ̀.+ (Sélà)   Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọ́run,+Ọkàn mi dúró ṣinṣin. Màá kọrin, màá sì lo ohun ìkọrin.   Jí, ìwọ ògo mi. Jí, ìwọ ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín; àti ìwọ náà, háàpù. Màá jí ní kùtùkùtù.+   Jèhófà, màá yìn ọ́ láàárín àwọn èèyàn;+Màá fi orin yìn ọ́* láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ 10  Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga gan-an, ó dé ọ̀run,+Òtítọ́ rẹ sì ga dé sánmà. 11  Kí a gbé ọ ga ju ọ̀run lọ, ìwọ Ọlọ́run;Kí ògo rẹ wà lórí gbogbo ayé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “kọ orin sí ọ.”