Sáàmù 35:1-28
Ti Dáfídì.
35 Jèhófà, gbèjà mi níwájú àwọn tó ń ta kò mí;+Dojú ìjà kọ àwọn tó ń bá mi jà.+
2 Gbé asà* rẹ àti apata ńlá,+Kí o sì dìde láti gbèjà mi.+
3 Yọ ọ̀kọ̀ rẹ àti àáké ogun* láti dojú kọ àwọn tó ń lépa mi.+
Sọ fún mi* pé: “Èmi ni ìgbàlà rẹ.”+
4 Kí ìtìjú bá àwọn tó ń dọdẹ ẹ̀mí mi,* kí wọ́n sì tẹ́.+
Kí àwọn tó ń gbèrò láti pa mí sá pa dà nínú ìtìjú.
5 Kí wọ́n dà bí ìyàngbò* nínú afẹ́fẹ́;Kí áńgẹ́lì Jèhófà lé wọn dà nù.+
6 Kí ọ̀nà wọn ṣókùnkùn, kí ó sì máa yọ̀ bọ̀rọ́Bí áńgẹ́lì Jèhófà ṣe ń lépa wọn.
7 Nítorí pé wọ́n ti dẹ àwọ̀n dè mí láìnídìí;Wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi* láìnídìí.
8 Kí àjálù dé bá a lójijì;Kí àwọ̀n tí ó dẹ mú òun fúnra rẹ̀;Kí ó kó sínú rẹ̀, kí ó sì pa run.+
9 Àmọ́ èmi* yóò máa yọ̀ nínú Jèhófà;Èmi yóò máa yọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ̀.
10 Gbogbo egungun mi á sọ pé:
“Jèhófà, ta ló dà bí rẹ?
Ò ń gba àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó lágbára jù wọ́n lọ,+O sì ń gba àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ àti tálákà lọ́wọ́ àwọn tó ń jà wọ́n lólè.”+
11 Àwọn ẹlẹ́rìí èké jáde wá,+Wọ́n ń bi mí ní àwọn ohun tí mi ò mọ̀.
12 Wọ́n ń fi ibi san rere fún mi,+Èyí sì mú kí n* máa ṣọ̀fọ̀.
13 Àmọ́ nígbà tí wọ́n ń ṣàìsàn, mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀,*Mo gbààwẹ̀ láti fi pọ́n ara mi* lójú,Nígbà tí àdúrà mi kò sì gbà,*
14 Mò ń rìn kiri, mo sì ń ṣọ̀fọ̀ bí ẹni tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ tàbí ọmọ ìyá rẹ̀ kú;Ìbànújẹ́ dorí mi kodò bí ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ ìyá rẹ̀.
15 Àmọ́ nígbà tí mo kọsẹ̀, inú wọn dùn, wọ́n sì kóra jọ;Wọ́n kóra jọ láti pa mí ní ibi tí wọ́n lúgọ sí dè mí;Wọ́n ya mí sí wẹ́wẹ́, wọn ò sì dákẹ́ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́.
16 Àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run fi mí ṣẹ̀sín,*Wọ́n ń wa eyín wọn pọ̀ sí mi.+
17 Jèhófà, ìgbà wo lo máa wò mí dà?+
Yọ mí* nínú ogun tí wọ́n gbé tì mí,+Gba ẹ̀mí mi tó ṣeyebíye* lọ́wọ́ àwọn ọmọ kìnnìún.*+
18 Nígbà náà, èmi yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nínú ìjọ ńlá;+Èmi yóò máa yìn ọ́ láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.
19 Má ṣe jẹ́ kí àwọn tó sọ ara wọn di ọ̀tá mi láìnídìí yọ̀ mí;Má ṣe jẹ́ kí àwọn tó kórìíra mi láìnídìí+ wò mí tìkà-tẹ̀gbin.+
20 Nítorí wọn kì í sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà,Ṣe ni wọ́n ń fẹ̀tàn hùmọ̀ ibi sí àwọn èèyàn àlàáfíà ilẹ̀ náà.+
21 Wọ́n lanu gbàù láti fẹ̀sùn kàn mí,Wọ́n sọ pé: “Àháà! Àháà! Ojú wa ti rí i.”
22 O ti rí èyí ná, Jèhófà. Má ṣe dákẹ́.+
Jèhófà, má jìnnà sí mi.+
23 Dìde, kí o sì wá gbèjà mi,Jèhófà, Ọlọ́run mi, gbèjà mi nínú ẹjọ́ mi.
24 Jèhófà Ọlọ́run mi, ṣe ìdájọ́ mi nítorí òdodo rẹ;+Má ṣe jẹ́ kí wọ́n yọ̀ mí.
25 Kí wọ́n má ṣe sọ fún ara wọn pé: “Àháà! Ọwọ́ wa ti tẹ ohun tí à ń fẹ́!”*
Kí wọ́n má ṣe sọ pé: “A ti gbé e mì.”+
26 Kí ojú ti gbogbo wọn, kí wọ́n sì tẹ́,Àwọn tó ń yọ̀ nítorí àjálù mi.
Kí àwọn tó ń gbé ara wọn ga sí mi gbé ìtìjú àti ẹ̀tẹ́ wọ̀ bí aṣọ.
27 Àmọ́ kí àwọn tí inú wọn ń dùn sí òdodo mi kígbe ayọ̀;Kí wọ́n máa sọ nígbà gbogbo pé:
“Kí a gbé Jèhófà ga, ẹni tí inú rẹ̀ ń dùn sí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ̀.”+
28 Nígbà náà, ahọ́n mi yóò máa ròyìn* òdodo rẹ,+Yóò sì máa yìn ọ́ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Apata kékeré tí àwọn tafàtafà sábà máa ń gbé dání.
^ Tàbí “àáké olórí méjì.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
^ Tàbí “bá pa dà sí àyà mi.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ń fini ṣẹ̀sín nítorí búrẹ́dì.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Ní Héb., “ọ̀kan ṣoṣo mi,” ó ń tọ́ka sí ọkàn rẹ̀ tàbí ẹ̀mí rẹ̀.
^ Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
^ Tàbí “Àháà! Ọkàn wa.”
^ Tàbí “ṣàṣàrò lórí.”

