Sáàmù 103:1-22
Ti Dáfídì.
103 Jẹ́ kí n* yin Jèhófà;Kí gbogbo ohun tó wà nínú mi yin orúkọ mímọ́ rẹ̀.
2 Jẹ́ kí n* yin Jèhófà;Kí n má gbàgbé gbogbo ohun tó ti ṣe láé.+
3 Ó ń dárí gbogbo àṣìṣe mi jì mí,+Ó sì ń wo gbogbo àìsàn mi sàn;+
4 Ó gba ẹ̀mí mi pa dà látinú kòtò,*+Ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti àánú dé mi ládé,+
5 Ó ń fi ohun rere tẹ́ mi lọ́rùn+ ní gbogbo ọjọ́ ayé mi,Kí agbára mi lè di ọ̀tun bíi ti ẹyẹ idì.+
6 Jèhófà ń fi òtítọ́ àti ìdájọ́ òdodo hùwà+Sí gbogbo àwọn tí à ń ni lára.+
7 Ó jẹ́ kí Mósè mọ àwọn ọ̀nà rẹ̀,+Ó sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.+
8 Aláàánú ni Jèhófà, ó sì ń gba tẹni rò,*+Kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀* sì pọ̀ gidigidi.+
9 Kì í fìgbà gbogbo wá àṣìṣe,+Kì í sì í bínú títí lọ.+
10 Kò fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa hùwà sí wa,+Kò sì fi ìyà tó yẹ àṣìṣe wa jẹ wá.+
11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga ju ayé,Bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ ṣe ga.+
12 Bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn,Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.+
13 Bí bàbá ṣe ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀,Bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń ṣàánú àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀.+
14 Nítorí ó mọ ẹ̀dá wa,+Ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.+
15 Ní ti ẹni kíkú, àwọn ọjọ́ rẹ̀ dà bíi ti koríko;+Ó rú jáde bí ìtànná orí pápá.+
16 Àmọ́ nígbà tí atẹ́gùn fẹ́, kò sí mọ́,Àfi bíi pé kò sí níbẹ̀ rí.*
17 Àmọ́ ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ wà títí ayé*Sí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀+Àti òdodo rẹ̀ sí àwọn ọmọ ọmọ wọn,+
18 Sí àwọn tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́+Àti àwọn tó ń rí i dájú pé àwọn pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
19 Jèhófà ti fìdí ìtẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in ní ọ̀run;+Ìjọba rẹ̀ sì ń ṣàkóso lórí ohun gbogbo.+
20 Ẹ yin Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin áńgẹ́lì rẹ̀,+ tí ẹ jẹ́ alágbára ńlá,Tí ẹ̀ ń ṣe ohun tó sọ,+ tí ẹ sì ń fetí sí ohùn rẹ̀.*
21 Ẹ yin Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀,+Ẹ̀yin òjíṣẹ́ rẹ̀ tó ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.+
22 Ẹ yin Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin iṣẹ́ rẹ̀,Ní gbogbo ibi tó ń jọba lé.*
Kí gbogbo ara* mi yin Jèhófà.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí “sàréè.”
^ Tàbí “jẹ́ olóore ọ̀fẹ́.”
^ Tàbí “inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”
^ Ní Héb., “Àyè rẹ̀ kò sì mọ̀ ọ́n mọ́.”
^ Tàbí “láti ayérayé dé ayérayé.”
^ Ní Héb., “tí ẹ sì ń gbọ́ ohùn (ìró) ọ̀rọ̀ rẹ̀.”
^ Tàbí “ibi tó wà lábẹ́ àṣẹ rẹ̀.”
^ Tàbí “ọkàn.”