Sáàmù 110:1-7

  • Ọba àti àlùfáà bíi ti Melikisédékì

    • ‘Máa jọba láàárín àwọn ọ̀tá rẹ’ (2)

    • Àwọn ọ̀dọ́ tó yọ̀ǹda ara wọn dà bí ìrì tó ń sẹ̀ (3)

Ti Dáfídì. Orin. 110  Jèhófà sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi+Títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”+   Jèhófà yóò na ọ̀pá agbára rẹ jáde láti Síónì, yóò sọ pé: “Máa ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá rẹ.”+   Àwọn èèyàn rẹ máa yọ̀ǹda ara wọn tinútinú ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ.* Nínú ọlá ńlá ìjẹ́mímọ́, láti ibi tí ọ̀yẹ̀ ti ń là,*O ní àwùjọ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n rí bí ìrì tó ń sẹ̀.   Jèhófà ti búra, kò sì ní pèrò dà,* ó ní: “Ìwọ jẹ́ àlùfáà títí láé+Ní ọ̀nà ti Melikisédékì!”+   Jèhófà yóò wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ;+Yóò fọ́ àwọn ọba túútúú ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀.+   Yóò mú ìdájọ́ ṣẹ lórí* àwọn orílẹ̀-èdè;+Yóò fi òkú kún ilẹ̀ náà.+ Yóò fọ́ aṣáájú* ilẹ̀ fífẹ̀* túútúú.   Yóò* mu omi odò tó wà lójú ọ̀nà,Yóò sì gbé orí rẹ̀ sókè.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ní ọjọ́ tí àwọn ọmọ ogun rẹ kóra jọ.”
Ní Héb., “láti ilé ọlẹ̀ ọ̀yẹ̀.”
Tàbí “yí ìpinnu rẹ̀ pa dà.”
Tàbí “láàárín.”
Ní Héb., “olórí.”
Tàbí “gbogbo ayé.”
Ó ń tọ́ka sí “Olúwa mi” inú ẹsẹ 1.