Sáàmù 115:1-18
115 Kì í ṣe àwa, Jèhófà, kì í ṣe àwa,*Àmọ́ orúkọ rẹ ni ògo yẹ+Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ.+
2 Ṣé ó yẹ kí àwọn orílẹ̀-èdè sọ pé:
“Ọlọ́run wọn dà?”+
3 Ọlọ́run wa wà ní ọ̀run;Ó ń ṣe ohun tí ó bá fẹ́.
4 Àwọn òrìṣà wọn jẹ́ fàdákà àti wúrà,Iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn.+
5 Wọ́n ní ẹnu, àmọ́ wọn ò lè sọ̀rọ̀;+Wọ́n ní ojú, àmọ́ wọn ò lè ríran;
6 Wọ́n ní etí, àmọ́ wọn ò lè gbọ́ràn;Wọ́n ní imú, àmọ́ wọn ò lè gbóòórùn;
7 Wọ́n ní ọwọ́, àmọ́ wọn ò lè fọwọ́ ba nǹkan;Wọ́n ní ẹsẹ̀, àmọ́ wọn ò lè rìn;+Wọn ò lè mú ìró kankan jáde láti ọ̀fun wọn.+
8 Àwọn tó ń ṣe wọ́n yóò dà bíi wọn gẹ́lẹ́,+Bẹ́ẹ̀ ló sì ṣe máa rí fún gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé wọn.+
9 Ísírẹ́lì, gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà+—Òun ni olùrànlọ́wọ́ wọn àti apata wọn.+
10 Ilé Áárónì,+ ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà—Òun ni olùrànlọ́wọ́ wọn àti apata wọn.
11 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Jèhófà, ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà+—Òun ni olùrànlọ́wọ́ wọn àti apata wọn.+
12 Jèhófà ń rántí wa, á sì bù kún wa;Á bù kún ilé Ísírẹ́lì;+Á bù kún ilé Áárónì.
13 Á bù kún àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà,Àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá.
14 Jèhófà máa mú kí ẹ pọ̀ sí i,Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ* yín.+
15 Kí Jèhófà bù kún yín,+Aṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé.+
16 Ní ti ọ̀run, ti Jèhófà ni,+Àmọ́ ayé ni ó fún àwọn ọmọ èèyàn.+
17 Àwọn òkú kì í yin Jáà;+Bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tó sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ìdákẹ́jẹ́ẹ́ ikú.*+
18 Àmọ́ a ó máa yin JáàLáti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.
Ẹ yin Jáà!*

