Sáàmù 54:1-7

  • Àdúrà ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ọ̀tá yí mi ká

    • “Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi” (4)

Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Másíkílì.* Ti Dáfídì, nígbà tí àwọn ọmọ Sífù wá sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, tí wọ́n sì sọ fún un pé: “Àárín wa ni Dáfídì fara pa mọ́ sí.”+ 54  Ọlọ́run, fi orúkọ rẹ gbà mí,+Sì fi agbára rẹ gbèjà mi.*+  2  Ọlọ́run, gbọ́ àdúrà mi;+Fetí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.  3  Nítorí àwọn àjèjì dìde sí mi,Àwọn ìkà ẹ̀dá sì ń wá ẹ̀mí* mi.+ Wọn ò ka Ọlọ́run sí.*+ (Sélà)  4  Wò ó! Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi;+Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn tó ń tì mí* lẹ́yìn.  5  Yóò san ìwà ìkà àwọn ọ̀tá mi pa dà fún wọn;+Pa wọ́n run* nínú òtítọ́ rẹ.+  6  Màá rúbọ sí ọ+ tinútinú. Màá yin orúkọ rẹ, Jèhófà, nítorí ó dára.+  7  Nítorí o gbà mí nínú gbogbo wàhálà,+Màá sì máa wo ìṣubú àwọn ọ̀tá mi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Tàbí “gba ẹjọ́ mi rò.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “Wọn kì í ro ti Ọlọ́run.”
^ Tàbí “ti ọkàn mi.”
^ Ní Héb., “Pa wọ́n lẹ́nu mọ́.”