Sáàmù 108:1-13

  • Àdúrà ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá

    • Asán ni ìgbàlà látọwọ́ èèyàn (12)

    • “Ọlọ́run ló máa fún wa lágbára” (13)

Orin. Orin Dáfídì. 108  Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọ́run. Màá fi gbogbo ara* kọrin, màá sì lo ohun ìkọrin.+   Jí, ìwọ ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín; àti ìwọ náà, háàpù.+ Màá jí ní kùtùkùtù.   Jèhófà, màá yìn ọ́ láàárín àwọn èèyàn,Màá sì fi orin yìn ọ́* láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.   Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga gan-an, ó dé ọ̀run,+Òtítọ́ rẹ sì ga dé sánmà.   Gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ, ìwọ Ọlọ́run;Kí ògo rẹ wà lórí gbogbo ayé.+   Kí a lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ sílẹ̀,Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbà wá sílẹ̀, kí o sì dá mi lóhùn.+   Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ nínú ìjẹ́mímọ́* rẹ̀ pé: “Màá yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun, màá fi Ṣékémù+ ṣe ogún fún àwọn èèyàn mi,Màá sì díwọ̀n Àfonífojì* Súkótù+ fún ẹni tí mo bá fẹ́.   Gílíádì+ jẹ́ tèmi, bí Mánásè ṣe jẹ́ tèmi,Éfúrémù sì ni akoto* orí mi;+Júdà ni ọ̀pá àṣẹ mi.+   Móábù ni bàsíà tí mo fi ń wẹ ẹsẹ̀.+ Orí Édómù ni màá ju bàtà mi sí.+ Màá kígbe ìṣẹ́gun lórí Filísíà.”+ 10  Ta ló máa mú mi wá sí ìlú olódi? Ta ló máa mú mi lọ sí Édómù?+ 11  Ìwọ Ọlọ́run tí o ti kọ̀ wá sílẹ̀ náà ni,Ìwọ Ọlọ́run wa, tí o kò bá àwọn ọmọ ogun wa jáde mọ́.+ 12  Ràn wá lọ́wọ́ nínú wàhálà wa,+Nítorí asán ni ìgbàlà látọwọ́ èèyàn.+ 13  Ọlọ́run ló máa fún wa lágbára,+Yóò sì tẹ àwọn ọ̀tá wa rẹ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “Kódà màá fi ògo mi.”
Tàbí “kọ orin sí ọ.”
Tàbí kó jẹ́, “ibi mímọ́.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé. Ní Héb., “odi agbára.”