Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A7-G

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù—Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí Jésù Ṣe Kẹ́yìn ní Jerúsálẹ́mù (Apá Kìíní)

ÀKÓKÒ

IBI

ÌṢẸ̀LẸ̀

MÁTÍÙ

MÁÀKÙ

LÚÙKÙ

JÒHÁNÙ

33, Nísàn 8

Bẹ́tánì

Jésù dé lọ́jọ́ mẹ́fà ṣáájú Ìrékọjá

     

11:55–12:1

Nísàn 9

Bẹ́tánì

Màríà da òróró sí orí àti ẹsẹ̀ rẹ̀

26:6-13

14:3-9

 

12:2-11

Bẹ́tánì sí Bẹtifágè sí Jerúsálẹ́mù

Ó wọ Jerúsálẹ́mù tiyì-tẹ̀yẹ, ó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́

21:1-11, 14-17

11:1-11

19:29-44

12:12-19

Nísàn 10

Bẹ́tánì sí Jerúsálẹ́mù

Ó gégùn-ún fún igi ọ̀pọ̀tọ́; ó fọ tẹ́ńpìlì mọ́ lẹ́ẹ̀kan sí i

21:18, 19; 21:12, 13

11:12-17

19:45, 46

 

Jerúsálẹ́mù

Àwọn àlùfáà àgbà àtàwọn akọ̀wé òfin gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù

 

11:18, 19

19:47, 48

 

Jèhófà sọ̀rọ̀; Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀; àsọtẹ́lẹ̀ tí Àìsáyà sọ nípa àìnígbàgbọ́ àwọn Júù ṣẹ

     

12:20-50

Nísàn 11

Bẹ́tánì sí Jerúsálẹ́mù

Ẹ̀kọ́ látara igi ọ̀pọ̀tọ́ tó rọ

21:19-22

11:20-25

   

Jerúsálẹ́mù, tẹ́ńpìlì

Wọ́n béèrè ẹni tó fún Jésù láṣẹ; àpèjúwe ọmọkùnrin méjì

21:23-32

11:27-33

20:1-8

 

Àwọn àpèjúwe: àwọn tó ń dáko tí wọ́n jẹ́ apààyàn, àsè ìgbéyàwó

21:33–22:14

12:1-12

20:9-19

 

Ó dáhùn ìbéèrè nípa Ọlọ́run àti Késárì, àjíǹde, àṣẹ tó tóbi jù lọ

22:15-40

12:13-34

20:20-40

 

Ó bi àwọn èrò bóyá Kristi jẹ́ ọmọ Dáfídì

22:41-46

12:35-37

20:41-44

 

Àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí gbé

23:1-39

12:38-40

20:45-47

 

Ó kíyè sí ohun tí opó kan fi ṣètọrẹ

 

12:41-44

21:1-4

 

Òkè Ólífì

Ó sọ àmì ìgbà tí òun máa wà níhìn-ín

24:1-51

13:1-37

21:5-38

 

Àwọn àpèjúwe: wúńdíá mẹ́wàá, tálẹ́ńtì, àgùntàn àti ewúrẹ́

25:1-46

     

Nísàn 12

Jerúsálẹ́mù

Àwọn aṣáájú Júù gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á

26:1-5

14:1, 2

22:1, 2

 

Júdásì ṣètò bó ṣe máa fà á lé wọn lọ́wọ́

26:14-16

14:10, 11

22:3-6

 

Nísàn 13 (Ọ̀sán Thursday)

Nítòsí àti nínú Jerúsálẹ́mù

Ó múra sílẹ̀ fún Ìrékọjá tó ṣe kẹ́yìn

26:17-19

14:12-16

22:7-13

 

Nísàn 14

Jerúsálẹ́mù

Ó bá àwọn àpọ́sítélì jẹ Ìrékọjá

26:20, 21

14:17, 18

22:14-18

 

Ó fọ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì

     

13:1-20