Sáàmù 71:1-24
71 Jèhófà, ìwọ ni mo fi ṣe ibi ààbò.
Má ṣe jẹ́ kí ojú tì mí láé.+
2 Gbà mí sílẹ̀, kí o sì gbà mí là nínú òdodo rẹ.
Tẹ́tí sí mi,* kí o sì gbà mí sílẹ̀.+
3 Di àpáta ààbò fún miKí n lè máa ríbi wọ̀ nígbà gbogbo.
Pàṣẹ láti gbà mí là,Nítorí ìwọ ni àpáta mi àti ibi ààbò mi.+
4 Ọlọ́run mi, gbà mí lọ́wọ́ ẹni burúkú,+Gbà mí lọ́wọ́ àwọn tó ń ni èèyàn lára láìtọ́.
5 Nítorí ìwọ ni ìrètí mi, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ;Ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé* láti ìgbà èwe mi wá.+
6 Ìwọ ni mo gbára lé láti ìgbà tí wọ́n ti bí mi;Ìwọ ló gbé mi jáde látinú ìyá mi.+
Gbogbo ìgbà ni mò ń yìn ọ́.
7 Mo dà bí iṣẹ́ ìyanu lójú ọ̀pọ̀ èèyàn,Àmọ́ ìwọ ni ibi ààbò mi tó lágbára.
8 Ìyìn rẹ kún ẹnu mi;+Mò ń sọ nípa ọlá ńlá rẹ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.
9 Má ṣe gbé mi sọ nù ní ọjọ́ ogbó mi;+Má pa mí tì nígbà tí mi ò bá lágbára mọ́.+
10 Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí mi,Àwọn tó sì fẹ́ gba ẹ̀mí* mi gbìmọ̀ pọ̀,+
11 Wọ́n ń sọ pé: “Ọlọ́run ti pa á tì.
Ẹ lé e, kí ẹ sì mú un, torí kò sẹ́ni tó máa gbà á sílẹ̀.”+
12 Ọlọ́run, má jìnnà sí mi.
Ìwọ Ọlọ́run mi, tètè wá ràn mí lọ́wọ́.+
13 Kí ojú ti àwọn tó ń ta kò mí,*Kí wọ́n sì ṣègbé.+
Ní ti àwọn tó ń wá àjálù mi,Kí ìtìjú àti ẹ̀tẹ́ bò wọ́n mọ́lẹ̀.+
14 Àmọ́ ní tèmi, èmi yóò máa dúró dè ọ́;Màá fi kún ìyìn rẹ.
15 Ẹnu mi yóò máa ròyìn òdodo rẹ+Àti àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n pọ̀ ju ohun tí mo lè lóye* lọ.+
16 Màá wá sọ nípa àwọn iṣẹ́ ńlá rẹ,Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ;Màá mẹ́nu kan òdodo rẹ, tìrẹ nìkan.
17 Ọlọ́run, o ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá,+Títí di báyìí, mò ń kéde àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.+
18 Kódà tí mo bá darúgbó, tí mo sì hu ewú, Ọlọ́run, má fi mí sílẹ̀.+
Jẹ́ kí n lè sọ nípa agbára* rẹ fún ìràn tó ń bọ̀,Kí n sì sọ nípa agbára ńlá rẹ fún gbogbo àwọn tó ń bọ̀.+
19 Ọlọ́run, òdodo rẹ ga dé òkè;+O ti ṣe àwọn ohun ńlá;Ọlọ́run, ta ló dà bí rẹ?+
20 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ti mú kí n rí ọ̀pọ̀ wàhálà àti àjálù,+Mú kí n sọ jí lẹ́ẹ̀kan sí i;Gbé mi dìde láti inú kòtò* ilẹ̀ ayé.+
21 Jẹ́ kí ọlá mi pọ̀ sí i,Rọ̀gbà yí mi ká, kí o sì tù mí nínú.
22 Nígbà náà, màá fi ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín yìn ọ́Nítorí òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi.+
Màá fi háàpù kọ orin ìyìn sí ọ,*Ìwọ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.
23 Ètè mi yóò máa kígbe ayọ̀ bí mo ṣe ń kọ orin ìyìn sí ọ,+Nítorí o gba ẹ̀mí mi là.*+
24 Ahọ́n mi yóò máa sọ nípa* òdodo rẹ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,+Ojú yóò ti àwọn tó ń wá ìparun mi, wọ́n á sì tẹ́.+

