Sáàmù 72:1-20

  • Àkóso Ọba tí Ọlọ́run yàn máa mú àlááfíà wá

    • “Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀” (7)

    • Àwọn ọmọ abẹ́ láti òkun dé òkun (8)

    • Yóò gbani lọ́wọ́ ìwà ipá (14)

    • Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ lórí ilẹ̀ (16)

    • A ó máa yin orúkọ Ọlọ́run títí láé (19)

Nípa Sólómọ́nì. 72  Ọlọ́run, sọ àwọn ìdájọ́ rẹ fún ọba,Kí o sì kọ́ ọmọ ọba ní òdodo rẹ.+  2  Kí ó fi òdodo gba ẹjọ́ àwọn èèyàn rẹ rò,Kí ó sì ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní.+  3  Kí àwọn òkè ńlá fún àwọn èèyàn ní àlàáfíà,Kí àwọn òkè kéékèèké sì mú òdodo wá.  4  Kí ó gbèjà* àwọn tó jẹ́ aláìní,Kí ó gba àwọn ọmọ òtòṣì là,Kí ó sì tẹ àwọn oníjìbìtì rẹ́.+  5  Láti ìran dé ìran,Wọ́n á máa bẹ̀rù rẹ níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ṣì wà,Tí òṣùpá sì ń yọ.+  6  Yóò dà bí òjò tó ń rọ̀ sórí koríko tí a gé,Bí ọ̀wààrà òjò tó ń mú kí ilẹ̀ rin.+  7  Ní àkókò rẹ̀, àwọn olódodo yóò gbilẹ̀,*+Àlàáfíà yóò sì gbilẹ̀+ títí òṣùpá kò fi ní sí mọ́.  8  Yóò ní àwọn ọmọ abẹ́* láti òkun dé òkunÀti láti Odò* dé àwọn ìkángun ayé.+  9  Àwọn tó ń gbé ní aṣálẹ̀ yóò tẹrí ba níwájú rẹ̀,Àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò sì lá erùpẹ̀.+ 10  Àwọn ọba Táṣíṣì àti ti àwọn erékùṣù yóò máa san ìṣákọ́lẹ̀.*+ Àwọn ọba Ṣébà àti ti Sébà yóò mú ẹ̀bùn wá.+ 11  Gbogbo àwọn ọba yóò tẹrí ba níwájú rẹ̀,Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa sìn ín. 12  Nítorí yóò gba àwọn aláìní tó ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀,Yóò sì gba tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. 13  Yóò ṣàánú aláìní àti tálákà,Yóò sì gba ẹ̀mí* àwọn tálákà là. 14  Yóò gbà wọ́n* lọ́wọ́ ìnira àti ìwà ipá,Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì ṣe iyebíye lójú rẹ̀. 15  Kí ó máa wà láàyè, kí a sì fún un ní wúrà Ṣébà.+ Kí a máa gbàdúrà fún un nígbà gbogbo,Kí a sì máa bù kún un láti àárọ̀ ṣúlẹ̀. 16  Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ* máa wà lórí ilẹ̀;+Ó máa kún àkúnwọ́sílẹ̀ lórí àwọn òkè. Èso rẹ̀ máa dára bíi ti Lẹ́bánónì,+Nínú àwọn ìlú, àwọn èèyàn máa pọ̀ bí ewéko ilẹ̀.+ 17  Kí orúkọ rẹ̀ wà títí láé,+Kí ó sì máa lókìkí níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ṣì wà. Kí àwọn èèyàn gba ìbùkún fún ara wọn nípasẹ̀ rẹ̀;+Kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè pè é ní aláyọ̀. 18  Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+Òun nìkan ló ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu.+ 19  Kí á yin orúkọ rẹ̀ ológo títí láé,+Kí ògo rẹ̀ sì kún gbogbo ayé.+ Àmín àti Àmín. 20  Ibí ni àdúrà Dáfídì, ọmọ Jésè+ parí sí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Ní Héb., “dá ẹjọ́.”
^ Ní Héb., “rú jáde.”
^ Tàbí “ṣàkóso.”
^ Ìyẹn, odò Yúfírétì.
^ Tàbí “owó òde.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ra ọkàn wọn pa dà.”
^ Tàbí “ọkà.”