Sáàmù 106:1-48
106 Ẹ yin Jáà!*
Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí ó jẹ́ ẹni rere;+Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.+
2 Ta ló lè kéde gbogbo iṣẹ́ ńlá tí Jèhófà ṣeTàbí tó lè kéde gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ tó yẹ fún ìyìn?+
3 Aláyọ̀ ni àwọn tó ń ṣe ohun tó bá ẹ̀tọ́ mu,Àwọn tó ń ṣe ohun tí ó tọ́ nígbà gbogbo.+
4 Jèhófà, rántí mi nígbà tí o bá ń ṣojú rere sí* àwọn èèyàn rẹ.+
Fi àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ tọ́jú mi,
5 Kí n lè gbádùn oore tí ò ń ṣe fún àwọn àyànfẹ́ rẹ,+Kí n lè máa bá orílẹ̀-èdè rẹ yọ̀,Kí n lè máa ṣògo bí mo ṣe ń yìn ọ́* pẹ̀lú ogún rẹ.
6 A ti dẹ́ṣẹ̀ bí àwọn baba ńlá wa;+A ti ṣe ohun tí kò dáa; a ti hùwà burúkú.+
7 Àwọn baba ńlá wa ní Íjíbítì kò mọyì* àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.
Wọn ò rántí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tó pọ̀ gidigidi,Wọ́n ṣọ̀tẹ̀ ní òkun, létí Òkun Pupa.+
8 Àmọ́, ó gbà wọ́n sílẹ̀ nítorí orúkọ rẹ̀,+Kí wọ́n lè mọ bí agbára rẹ̀ ṣe pọ̀ tó.+
9 Ó bá Òkun Pupa wí, ó sì gbẹ;Ó mú wọn gba ìsàlẹ̀ rẹ̀ bí ẹni gba aṣálẹ̀* kọjá;+
10 Ó gbà wọ́n lọ́wọ́ elénìní,+Ó sì gbà wọ́n pa dà lọ́wọ́ ọ̀tá.+
11 Omi bo àwọn elénìní wọn;Kò sí ìkankan lára wọn tó yè bọ́.*+
12 Nígbà náà, wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí rẹ̀;+Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin yìn ín.+
13 Àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n fi gbàgbé ohun tó ṣe;+Wọn ò dúró de ìmọ̀ràn rẹ̀.
14 Wọ́n jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gbà wọ́n lọ́kàn ní aginjù;+Wọ́n dán Ọlọ́run wò ní aṣálẹ̀.+
15 Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè,Àmọ́ lẹ́yìn náà, ó fi àrùn kọ lù wọ́n, wọ́n* sì rù hangogo.+
16 Ní ibùdó, wọ́n jowú MósèÀti Áárónì,+ ẹni mímọ́ Jèhófà.+
17 Ni ilẹ̀ bá lanu, ó gbé Dátánì mì,Ó sì bo àwọn tó kóra jọ sọ́dọ̀ Ábírámù.+
18 Iná sọ láàárín àwùjọ wọn;Ọwọ́ iná jó àwọn ẹni burúkú run.+
19 Wọ́n ṣe ère ọmọ màlúù kan ní Hórébù,Wọ́n sì forí balẹ̀ fún ère onírin;*+
20 Wọ́n gbé ògo miFún ère akọ màlúù tó ń jẹ koríko.+
21 Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run,+ Olùgbàlà wọn,Ẹni tó ṣe àwọn ohun ńlá ní Íjíbítì,+
22 Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu ní ilẹ̀ Hámù,+Àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù ní Òkun Pupa.+
23 Díẹ̀ ló kù kó sọ pé kí wọ́n pa wọ́n rẹ́,Àmọ́ Mósè àyànfẹ́ rẹ̀ bá wọn bẹ̀bẹ̀*Láti yí ìbínú rẹ̀ tó ń pani run pa dà.+
24 Síbẹ̀, wọn ò ka ilẹ̀ dáradára náà sí;+Wọn ò nígbàgbọ́ nínú ìlérí rẹ̀.+
25 Ṣe ni wọ́n ń ráhùn nínú àgọ́ wọn;+Wọn ò fetí sí ohùn Jèhófà.+
26 Torí náà, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti búra nípa wọnPé òun máa mú kí wọ́n ṣubú ní aginjù;+
27 Pé òun máa mú kí àtọmọdọ́mọ wọn ṣubú láàárín àwọn orílẹ̀-èdèÀti pé òun máa tú wọn ká sí àwọn ilẹ̀ náà.+
28 Lẹ́yìn náà, wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń sin* Báálì Péórì,+Wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òkú.*
29 Wọ́n fi àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe mú Un bínú,+Àjàkálẹ̀ àrùn sì bẹ́ sílẹ̀ láàárín wọn.+
30 Àmọ́ nígbà tí Fíníhásì dìde, tí ó sì dá sí i,Àjàkálẹ̀ àrùn náà dáwọ́ dúró.+
31 A sì kà á sí òdodo fún unLáti ìran dé ìran àti títí láé.+
32 Wọ́n múnú bí I níbi omi Mẹ́ríbà,*Wọ́n sì fi tiwọn kó bá Mósè.+
33 Wọ́n gbé ẹ̀mí rẹ̀ gbóná,Ó sì fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ láìronú.+
34 Wọn ò pa àwọn èèyàn náà run,+Bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún wọn.+
35 Àmọ́ wọ́n ń bá àwọn orílẹ̀-èdè náà ṣe wọlé wọ̀de,+Wọ́n sì ń hùwà bíi tiwọn.*+
36 Wọ́n ń sin àwọn òrìṣà wọn,+Àwọn òrìṣà náà sì di ìdẹkùn fún wọn.+
37 Wọ́n ń fi àwọn ọmọkùnrin wọnÀti àwọn ọmọbìnrin wọn rúbọ sí àwọn ẹ̀mí èṣù.+
38 Wọ́n ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,+Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin wọn àti ti àwọn ọmọbìnrin wọnTí wọ́n fi rúbọ sí àwọn òrìṣà Kénáánì;+Ilẹ̀ náà sì di ẹlẹ́gbin nítorí ìtàjẹ̀sílẹ̀.
39 Àwọn iṣẹ́ wọn sọ wọ́n di aláìmọ́,Wọ́n sì ṣe àgbèrè ẹ̀sìn.+
40 Torí náà, ìbínú Jèhófà ru sí àwọn èèyàn rẹ̀,Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kórìíra ogún rẹ̀.
41 Léraléra ló fi wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́,+Kí àwọn tó kórìíra wọn lè ṣàkóso lé wọn lórí.+
42 Àwọn ọ̀tá wọn ni wọ́n lára,Wọ́n sì jẹ gàba lé wọn lórí.*
43 Ọ̀pọ̀ ìgbà ló gbà wọ́n sílẹ̀,+Àmọ́ wọ́n á ṣọ̀tẹ̀, wọ́n á sì ṣàìgbọràn,+A ó sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí àṣìṣe wọn.+
44 Àmọ́ á tún rí ìdààmú tó bá wọn,+Á sì gbọ́ igbe ìrànlọ́wọ́ wọn.+
45 Nítorí wọn, á rántí májẹ̀mú rẹ̀,Àánú á sì ṣe é* nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tó ga tí kì í sì í yẹ̀.*+
46 Á jẹ́ kí àánú wọn máa ṣeGbogbo àwọn tó mú wọn lẹ́rú.+
47 Gbà wá, Jèhófà Ọlọ́run wa,+Kí o sì kó wa jọ látinú àwọn orílẹ̀-èdè+Ká lè máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ,Ká sì máa yọ̀ bí a ṣe ń yìn ọ́.*+
48 Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lìTítí láé àti láéláé.*+
Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, “Àmín!”*
Ẹ yin Jáà!*
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
^ Tàbí “ṣoore fún.”
^ Tàbí “máa fi ọ́ yangàn.”
^ Tàbí “lóye ìtúmọ̀.”
^ Tàbí “aginjù.”
^ Tàbí “tó ṣẹ́ kù.”
^ Tàbí “ọkàn wọn.”
^ Tàbí “ère dídà.”
^ Ní Héb., “dúró sí àlàfo níwájú rẹ̀.”
^ Tàbí “so ara wọn mọ́.”
^ Ìyẹn, ẹbọ tí wọ́n rú sí òkú èèyàn tàbí sí àwọn ọlọ́run tí kò lẹ́mìí.
^ Ó túmọ̀ sí “Ìjà.”
^ Tàbí “Wọ́n sì kọ́ ìṣe wọn.”
^ Ní Héb., “Wọ́n sì wà lábẹ́ ọwọ́ wọn.”
^ Tàbí “Á kẹ́dùn.”
^ Tàbí “ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ tó pọ̀ gidigidi.”
^ Tàbí “yọ̀ nínú ìyìn rẹ.”
^ Tàbí “Láti ayérayé dé ayérayé.”
^ Tàbí “Kó rí bẹ́ẹ̀!”
^ Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

