Sáàmù 69:1-36
Sí olùdarí; kí a yí i sí “Òdòdó Lílì.” Ti Dáfídì.
69 Gbà mí là, Ọlọ́run, torí pé omi ti fẹ́ gba ẹ̀mí mi.*+
2 Mo ti rì sínú ẹrẹ̀ tó jìn, níbi tí kò sí ilẹ̀ tó ṣeé dúró lé.+
Mo ti dé inú ibú omi,Odò tó ń yára ṣàn sì gbé mi lọ.+
3 Ó ti rẹ̀ mí nítorí igbe tí mò ń ké;+Ọ̀fun mi ti há.
Ojú mi ti di bàìbàì bí mo ṣe ń dúró de Ọlọ́run mi.+
4 Àwọn tó kórìíra mi láìnídìí+Pọ̀ ju irun orí mi lọ.
Àwọn tó fẹ́ pa mí,Àwọn oníbékebèke tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá mi* ti pọ̀ gan-an.
Àwọn nǹkan tí mi ò jí ni wọ́n ní kí n dá pa dà tipátipá.
5 Ọlọ́run, o mọ ìwà òmùgọ̀ mi,Ẹ̀bi mi kò sì pa mọ́ lójú rẹ.
6 Kí àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé ọ má ṣe rí ìtìjú nítorí tèmi,Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.
Kí àwọn tó ń wá ọ má ṣe tẹ́ nítorí tèmi,Ìwọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
7 Wọ́n pẹ̀gàn mi nítorí rẹ;+Ẹ̀tẹ́ bá mi.+
8 Mo ti di àlejò sí àwọn arákùnrin mi,Mo sì ti di àjèjì sí àwọn ọmọ ìyá mi.+
9 Ìtara ilé rẹ ti gbà mí lọ́kàn,+Ẹ̀gàn ẹnu àwọn tó ń pẹ̀gàn rẹ sì ti wá sórí mi.+
10 Nígbà tí mo rẹ ara* mi sílẹ̀ pẹ̀lú ààwẹ̀ gbígbà,*Wọ́n pẹ̀gàn mi nítorí èyí.
11 Nígbà tí mo gbé aṣọ ọ̀fọ̀* wọ̀,Mo di ẹni ẹ̀gàn* lójú wọn.
12 Èmi ni àwọn tó ń jókòó ní ẹnubodè fi ń ṣe ọ̀rọ̀ sọ,Ọ̀rọ̀ mi sì ni àwọn ọ̀mùtí fi ń ṣe orin kọ.
13 Àmọ́, kí àdúrà mi wá sọ́dọ̀ rẹ,Jèhófà, ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà.+
Nínú ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ìwọ Ọlọ́run,Fi àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ dá mi lóhùn.+
14 Yọ mí nínú ẹrẹ̀;Má ṣe jẹ́ kí n rì.
Gbà mí lọ́wọ́ àwọn tó kórìíra miKí o sì yọ mí nínú ibú omi.+
15 Má ṣe jẹ́ kí omi tó ń yára ṣàn gbé mi lọ,+Tàbí kí ibú omi bò mí mọ́lẹ̀,Tàbí kí kànga* pa dé mọ́ mi.+
16 Dá mi lóhùn, Jèhófà, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára.+
Nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ, yíjú sí mi,+
17 Má sì fi ojú rẹ pa mọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ.+
Tètè dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú wàhálà.+
18 Sún mọ́ mi, kí o sì gbà mí sílẹ̀;*Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
19 O mọ ẹ̀gàn, ìtìjú àti ẹ̀tẹ́ tó bá mi.+
O rí gbogbo àwọn ọ̀tá mi.
20 Ẹ̀gàn ti dá ọgbẹ́ sí mi lọ́kàn, ọgbẹ́ náà kò sì ṣeé wò sàn.*
Mò ń retí pé màá rí ẹni bá mi kẹ́dùn, àmọ́ kò sí,+Mo sì ń retí pé màá rí olùtùnú, àmọ́ mi ò rí ìkankan.+
21 Májèlé* ni wọ́n fún mi dípò oúnjẹ,+Ọtí kíkan ni wọ́n sì fún mi láti fi pa òùngbẹ.+
22 Jẹ́ kí tábìlì wọn di pańpẹ́ fún wọn,Kí aásìkí wọn sì di ìdẹkùn.+
23 Jẹ́ kí ojú wọn ṣú, kí wọ́n má lè ríran,Sì mú kí ẹsẹ̀* wọn máa gbọ̀n nígbà gbogbo.
24 Da ìbínú* rẹ sí wọn lórí,Sì mú kí ìbínú rẹ tó ń jó bí iná dé bá wọn.+
25 Jẹ́ kí ibùdó wọn* di ahoro;Kí ó má ṣe sí ẹnì kankan tí á máa gbé inú àgọ́ wọn.+
26 Nítorí ẹni tí o ti lù ni wọ́n ń lépa,Wọ́n sì ń sọ nípa ìrora àwọn tí o ṣe léṣe.
27 Jẹ́ kí wọ́n jẹ ẹ̀bi lé ẹ̀bi,Kí wọ́n má sì ní ìpín kankan nínú òdodo rẹ.
28 Jẹ́ kí a pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò nínú ìwé àwọn alààyè,*+Kí a má sì kọ orúkọ wọn mọ́ àwọn olódodo.+
29 Ní tèmi, ìyà ń jẹ mí, mo sì wà nínú ìrora.+
Ìwọ Ọlọ́run, kí agbára rẹ tó ń gbani là dáàbò bò mí.
30 Màá kọ orin ìyìn sí orúkọ Ọlọ́run,Màá sì fi ọpẹ́ gbé e ga.
31 Èyí máa mú inú Jèhófà dùn ju akọ màlúù,Ju akọ ọmọ màlúù tó ní ìwo àti pátákò.+
32 Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ yóò rí i, wọ́n á sì yọ̀.
Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá Ọlọ́run, kí ọkàn yín sọ jí.
33 Nítorí Jèhófà ń fetí sí àwọn aláìní,+Kò sì ní fojú pa àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà lóko ẹrú rẹ́.+
34 Kí ọ̀run àti ayé máa yìn ín,+Àwọn òkun àti ohun gbogbo tó ń rìn nínú wọn.
35 Ọlọ́run yóò gba Síónì là,+Yóò tún àwọn ìlú Júdà kọ́,Wọ́n á máa gbé ibẹ̀, àwọn ni yóò sì ni ín.*
36 Àtọmọdọ́mọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò jogún rẹ̀,+Àwọn tó fẹ́ràn orúkọ rẹ̀ + yóò sì máa gbé inú rẹ̀.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ọkàn mi ti fẹ́ bómi lọ.”
^ Tàbí “Àwọn tó di ọ̀tá mi láìnídìí.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Nígbà tí mo sunkún tí mo sì gbààwẹ̀.”
^ Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
^ Ní Héb., “àfipòwe.”
^ Tàbí “kòtò.”
^ Tàbí “Sún mọ́ ọkàn mi, kí o sì gbà á pa dà.”
^ Tàbí “ó le débi pé ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi.”
^ Tàbí “Ewéko onímájèlé.”
^ Ní Héb., “ìbàdí.”
^ Tàbí “ìrunú.”
^ Tàbí “ibùdó wọn tó ní ògiri yí ká.”
^ Tàbí “ìwé ìyè.”
^ Ìyẹn, ilẹ̀ náà.

