Sáàmù 81:1-16

  • Ọlọ́run rọ àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n ṣègbọràn

    • Ẹ má ṣe sin àwọn ọlọ́run àjèjì (9)

    • ‘Ká ní ẹ lè fetí sí mi’ (13)

Sí olùdarí; lórí Gítítì.* Ti Ásáfù.+ 81  Ẹ kígbe ayọ̀ sí Ọlọ́run tó jẹ́ agbára wa.+ Ẹ kígbe ìṣẹ́gun sí Ọlọ́run Jékọ́bù.   Ẹ bẹ̀rẹ̀ orin, ẹ gbé ìlù tanboríìnì,Háàpù tó ń dún dáadáa àti ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín.   Ẹ fun ìwo nígbà òṣùpá tuntun,+Nígbà òṣùpá àrànmọ́jú, nítorí ọjọ́ àjọyọ̀ wa.+   Nítorí pé òfin ló jẹ́ fún Ísírẹ́lì,Àṣẹ Ọlọ́run Jékọ́bù.+   Ó fi í ṣe ìrántí fún Jósẹ́fù+Nígbà tí Ó jáde lọ láti dojú kọ ilẹ̀ Íjíbítì.+ Mo gbọ́ ohùn* kan tí mi ò mọ̀, tó sọ pé:   “Mo gbé ẹrù kúrò ní èjìká rẹ̀;+Mo gba apẹ̀rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.   O pè mí nínú wàhálà tó bá ọ, mo sì gbà ọ́ sílẹ̀;+Mo dá ọ lóhùn láti ojú ọ̀run tó ń sán ààrá.*+ Mo dán ọ wò níbi omi Mẹ́ríbà.*+ (Sélà)   Ẹ gbọ́, ẹ̀yin èèyàn mi, màá ta kò yín. Ìwọ Ísírẹ́lì, ká ní o lè fetí sí mi.+   Kò ní sí ọlọ́run àjèjì láàárín rẹ,O kò sì ní forí balẹ̀ fún ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè.+ 10  Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ,Ẹni tó mú ọ jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ La gbogbo ẹnu rẹ, màá sì fi oúnjẹ kún un.+ 11  Àmọ́ àwọn èèyàn mi ò fetí sí ohùn mi;Ísírẹ́lì kò ṣègbọràn sí mi.+ 12  Torí náà, mo jẹ́ kí wọ́n máa ṣe ohun tí agídí ọkàn wọn sọ;Wọ́n ń ṣe ohun tí wọ́n rò pé ó tọ́.*+ 13  Ká ní àwọn èèyàn mi lè fetí sí mi,+Ká ní Ísírẹ́lì lè rìn ní àwọn ọ̀nà mi!+ 14  Kíákíá ni mi ò bá ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn;Mi ò bá yí ọwọ́ mi pa dà sí àwọn elénìní wọn.+ 15  Àwọn tó kórìíra Jèhófà yóò ba búrúbúrú níwájú rẹ̀,Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn* yóò sì wà títí láé. 16  Àmọ́ yóò fi àlìkámà* tó dára jù lọ* bọ́ ọ,*+Yóò sì fi oyin inú àpáta tẹ́ ọ lọ́rùn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “èdè.”
Ó túmọ̀ sí “Ìjà.”
Ní Héb., “láti ibi tí ààrá fara pa mọ́ sí.”
Ní Héb., “Wọ́n rìn nínú ìmọ̀ràn ara wọn.”
Ní Héb., “Ìgbà wọn.”
Tàbí “wíìtì.”
Ní Héb., “ọ̀rá àlìkámà.”
Ní Héb., “ọ,” ìyẹn, àwọn èèyàn Ọlọ́run.