Jóòbù 26:1-14

  • Jóòbù fèsì (1-14)

    • “Wo bí o ṣe ran ẹni tí kò lágbára lọ́wọ́!” (1-4)

    • ‘Ọlọ́run fi ayé rọ̀ sórí òfo’ (7)

    • ‘Bíńtín lára àwọn ọ̀nà Ọlọ́run’ (14)

26  Jóòbù wá fèsì pé:   “Wo bí o ṣe ran ẹni tí kò lágbára lọ́wọ́! Wo bí o ṣe gba apá tí kò lókun là!+   Wo ìmọ̀ràn tó dáa gan-an tí o fún ẹni tí kò gbọ́n!+ Wo bí o ṣe fi ọgbọ́n rẹ tó gbéṣẹ́* hàn ní fàlàlà!*   Ta lò ń gbìyànjú láti bá sọ̀rọ̀,Ta ló sì mí sí ọ tí o fi ń sọ àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀?*   Jìnnìjìnnì bá àwọn tí ikú ti pa;*Wọ́n tiẹ̀ tún rẹlẹ̀ ju omi àtàwọn tó ń gbénú wọn.   Ìhòòhò ni Isà Òkú* wà níwájú Ọlọ́run,*+Ibi ìparun* sì wà láìfi ohunkóhun bò ó.   Ó na òfúrufú apá àríwá* sórí ibi tó ṣófo,*+Ó fi ayé rọ̀ sórí òfo;   Ó wé omi mọ́ inú àwọsánmà* rẹ̀,+Débi pé àwọsánmà ò bẹ́, bí wọ́n tiẹ̀ wúwo;   Ó bo ìtẹ́ rẹ̀ ká má bàa rí i,Ó na sánmà rẹ̀ bò ó.+ 10  Ó pààlà* sójú òfúrufú àti omi;+Ó fi ààlà sáàárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn. 11  Àní àwọn òpó ọ̀run mì tìtì;Ìbáwí rẹ̀ mú wọn wárìrì. 12  Ó fi agbára rẹ̀ ru òkun sókè,+Ó sì fi òye rẹ̀ fọ́ ẹran ńlá inú òkun* sí wẹ́wẹ́.+ 13  Ó fi èémí* rẹ̀ mú kí ojú ọ̀run mọ́ lóló;Ọwọ́ rẹ̀ ń gún ejò tó ń yọ́ bọ́rọ́.* 14  Wò ó! Bíńtín lèyí jẹ́ lára àwọn ọ̀nà rẹ̀;+Ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lásán ló ta sí wa létí nípa rẹ̀! Ta ló wá lè lóye ààrá ńlá rẹ̀?”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “làákàyè rẹ.”
Tàbí “lọ́pọ̀ yanturu.”
Ní Héb., “Èémí (ẹ̀mí) ta ló sì ti ọ̀dọ̀ rẹ jáde?”
Tàbí “ti sọ di aláìlágbára.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “rẹ̀.”
Tàbí “Ábádónì.”
Ní Héb., “òfìfo.”
Ní Héb., “àríwá.”
Tàbí “ìkùukùu.”
Ní Héb., “Ó ṣe òbìrìkìtì.”
Ní Héb., “Ráhábù.”
Tàbí “atẹ́gùn.”
Tàbí “tó ń yára lọ.”