Jóòbù 6:1-30

  • Jóòbù fèsì (1-30)

    • Ó sọ pé òun ò jẹ̀bi bí òun ṣe ń ké jáde (2-6)

    • Ọ̀dàlẹ̀ ni àwọn tó ń tù ú nínú (15-18)

    • “Òótọ́ ọ̀rọ̀ kì í dunni!” (25)

6  Jóòbù wá fèsì pé:   “Ká ní wọ́n lè díwọ̀n ìrora mi+ látòkè délẹ̀ ni,Kí wọ́n sì gbé òun àti àjálù mi sórí òṣùwọ̀n!   Ó ti wá wúwo ju iyanrìn òkun lọ báyìí. Ìdí nìyẹn tí ọ̀rọ̀ mi fi jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹhànnà.*+   Torí àwọn ọfà Olódùmarè ti gún mi,Ẹ̀mí mi sì ń mu oró wọn;+Ohun tó ń fa ìpayà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ti kóra jọ lòdì sí mi.   Ṣé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó+ máa ké tó bá rí koríko jẹ,Àbí ṣé akọ màlúù máa dún tó bá rí oúnjẹ ẹran jẹ?   Ṣé èèyàn lè jẹ oúnjẹ tí kò dùn láìfi iyọ̀ sí i,Àbí ṣé adùn wà nínú omi ewéko málò?   Mi* ò fọwọ́ kan irú àwọn nǹkan yẹn. Wọ́n dà bí ohun tó ba oúnjẹ mi jẹ́.   Ká ní ọwọ́ mi lè tẹ ohun tí mo béèrè ni,Kí Ọlọ́run sì ṣe ohun tí mo fẹ́ fún mi!   Pé kí Ọlọ́run ṣe tán láti tẹ̀ mí rẹ́,Kó na ọwọ́ rẹ̀, kó sì pa mí dà nù!+ 10  Torí ìyẹn gan-an máa tù mí nínú;Màá fò sókè tayọ̀tayọ̀ láìka ìrora tí kò lọ sí,Torí mi ò sọ pé irọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́.+ 11  Ṣé agbára mi gbé e láti máa dúró?+ Òpin wo ló máa dé bá mi, tí màá ṣì fi wà láàyè?* 12  Ṣé mo lágbára bí òkúta? Àbí bàbà ni ẹran ara mi? 13  Ṣé mo lè ran ara mi lọ́wọ́ rárá,Nígbà tí a ti lé gbogbo ohun tí mo fi ń ti ara mi lẹ́yìn jìnnà sí mi? 14  Ẹnikẹ́ni tí kò bá fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹnì kejì rẹ̀,+Kò ní bẹ̀rù Olódùmarè.+ 15  Àwọn arákùnrin mi ti di ọ̀dàlẹ̀+ bí odò ìgbà òtútù,Bí àwọn omi odò ìgbà òtútù tó gbẹ. 16  Yìnyín mú kó ṣókùnkùn,Yìnyín tó sì ń yọ́ fara pa mọ́ sínú wọn. 17  Àmọ́ ní àsìkò tó yẹ, wọn ò lómi mọ́, wọ́n sì wá sí òpin;Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, wọ́n gbẹ dà nù. 18  Ipa odò wọn gba ibòmíì;Wọ́n ṣàn lọ sínú aṣálẹ̀, wọ́n sì dópin. 19  Àwọn ará Témà+ tí wọ́n ń rìnrìn àjò ń wá wọn,Àwọn arìnrìn-àjò láti Ṣébà*+ ń dúró dè wọ́n. 20  Ojú tì wọ́n torí pé ìgbẹ́kẹ̀lé wọn ti dòfo;Wọ́n dé ibẹ̀, àmọ́ òfo ni wọ́n bá. 21  Bí ẹ̀yin náà ṣe wá rí lójú mi nìyẹn;+Ẹ rí bí àjálù tó bá mi ṣe le tó,* ẹ̀rù sì bà yín.+ 22  Ṣé mo sọ pé, ‘Ẹ fún mi ní nǹkan,’Àbí mo tọrọ ẹ̀bùn látinú ọrọ̀ yín? 23  Ṣé mo ní kí ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá,Àbí mo ní kí ẹ gbà mí* lọ́wọ́ àwọn tó ń fìyà jẹ mí? 24  Ẹ kọ́ mi, màá sì dákẹ́;+Ẹ jẹ́ kí n mọ àṣìṣe mi. 25  Òótọ́ ọ̀rọ̀ kì í dunni!+ Àmọ́ kí ni ìbáwí yín wúlò fún?+ 26  Ṣé ẹ̀ ń gbèrò láti bá mi wí torí ọ̀rọ̀ mi ni,Ọ̀rọ̀ tí ẹni tí ìdààmú bá ń sọ,+ tí afẹ́fẹ́ sì ń fẹ́ dà nù? 27  Ẹ máa ṣẹ́ kèké lé ọmọ aláìlóbìí*+ pàápàá,Ẹ sì máa ta ọ̀rẹ́ yín!*+ 28  Torí náà, ẹ yíjú wò mí,Mi ò ní parọ́ fún yín. 29  Ẹ jọ̀ọ́, ẹ tún inú rò, ẹ má ṣe dá mi lẹ́bi,Àní, ẹ tún inú rò, torí òdodo mi ò tíì yí pa dà. 30  Ṣé ahọ́n mi ń sọ ohun tí kò tọ́ ni? Ṣé agbára ìtọ́wò ẹnu mi ò mọ̀ pé nǹkan ti ṣẹlẹ̀ ni?

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọ̀rọ̀ tó le, tí mo sọ láìronú jinlẹ̀.”
Tàbí “Ọkàn mi.”
Tàbí “tí màá fi jẹ́ kí ẹ̀mí (ọkàn) mi gùn.”
Tàbí “Àwùjọ arìnrìn-àjò àwọn Sábéà.”
Ní Héb., “Ẹ rí ẹ̀rù àjálù mi.”
Ní Héb., “rà mí pa dà.”
Tàbí “aláìníbaba.”
Tàbí “fi ọ̀rẹ́ yín gba pààrọ̀.”