Jóòbù 34:1-37

  • Élíhù gbé ìdájọ́ àtàwọn ọ̀nà Ọlọ́run ga (1-37)

    • Jóòbù ní Ọlọ́run fi ìdájọ́ òdodo du òun (5)

    • Ọlọ́run tòótọ́ kì í hùwà burúkú (10)

    • Jóòbù ò ní ìmọ̀ (35)

34  Élíhù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé:   “Ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n;Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ẹ mọ nǹkan púpọ̀.   Torí etí máa ń dán ọ̀rọ̀ wò,Bí ahọ́n* ṣe ń tọ́ oúnjẹ wò.   Ẹ jẹ́ ká fúnra wa ṣàyẹ̀wò ohun tó tọ́;Ẹ jẹ́ ká pinnu ohun tó dáa láàárín ara wa.   Torí Jóòbù sọ pé, ‘Mo jàre,+Àmọ́ Ọlọ́run ti fi ìdájọ́ òdodo dù mí.+   Ṣé màá parọ́ nípa ẹjọ́ tó yẹ kí wọ́n dá fún mi ni? Ọgbẹ́ mi ò ṣeé wò sàn, bí mi ò tiẹ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.’+   Èèyàn míì wo ló dà bíi Jóòbù,Tó ń mu ẹ̀gàn bí ẹni mu omi?   Ó ń bá àwọn aṣebi kẹ́gbẹ́,Ó sì ń bá àwọn èèyàn burúkú ṣe wọlé wọ̀de.+   Torí o sọ pé, ‘Èèyàn kì í jèrèTó bá ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.’+ 10  Torí náà, ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin tí ẹ ní òye:* Ó dájú pé Ọlọ́run tòótọ́ kò ní hùwà burúkú,+Pé Olódùmarè kò ní ṣe ohun tí kò dáa!+ 11  Torí ó máa fi ohun tí èèyàn bá ṣe san án lẹ́san,+Ó sì máa mú kó jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. 12  Torí ó dájú pé, Ọlọ́run kì í hùwà burúkú;+Olódùmarè kì í sì í yí ìdájọ́ po.+ 13  Ta ló fi ayé sí ìkáwọ́ rẹ̀,Ta ló sì fi ṣe olórí gbogbo ayé?* 14  Tó bá fiyè* sí wọn,Tó bá kó ẹ̀mí àti èémí wọn jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,+ 15  Gbogbo èèyàn* jọ máa ṣègbé,Aráyé á sì pa dà sí erùpẹ̀.+ 16  Torí náà, tí o bá ní òye, fiyè sí èyí;Fetí sí ọ̀rọ̀ mi dáadáa. 17  Ṣé ó yẹ kí ẹni tó kórìíra ìdájọ́ òdodo jẹ́ olórí,Àbí o máa dá alágbára tó jẹ́ olódodo lẹ́bi? 18  Ṣé o máa sọ fún ọba pé, ‘O ò wúlò fún ohunkóhun,’Àbí fún àwọn èèyàn pàtàkì pé, ‘Ẹni burúkú ni yín’?+ 19  Ẹnì kan wà tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn olórí,Tí kì í sì í ka ọlọ́rọ̀ sí ju aláìní lọ,*+Torí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn.+ 20  Wọ́n lè kú lójijì,+ láàárín òru;+Wọ́n gbọ̀n rìrì, wọ́n sì gbẹ́mìí mì;A mú àwọn alágbára pàápàá kúrò, àmọ́ kì í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn.+ 21  Torí ojú Ọlọ́run ń wo àwọn ọ̀nà èèyàn,+Ó sì ń rí gbogbo ìṣísẹ̀ rẹ̀. 22  Kò sí òkùnkùn tàbí ibi tó ṣókùnkùn biribiriTí àwọn aṣebi máa fara pa mọ́ sí.+ 23  Torí Ọlọ́run kò yan àkókò fún èèyàn kankanPé kó wá síwájú òun fún ìdájọ́. 24  Ó ń fọ́ àwọn alágbára túútúú láì ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣèwádìí,Ó sì ń fi àwọn míì rọ́pò wọn.+ 25  Torí ó mọ ohun tí wọ́n ń ṣe;+Ó ń bì wọ́n ṣubú ní òru, wọ́n sì pa run.+ 26  Ó kọ lù wọ́n torí ìwà burúkú wọn,Níbi tí gbogbo ojú ti lè rí i,+ 27  Torí wọ́n ti yí pa dà, wọn ò tẹ̀ lé e mọ́,+Wọn ò sì ka àwọn ọ̀nà rẹ̀ sí;+ 28  Wọ́n mú kí àwọn aláìní ké pè é,Tó fi gbọ́ igbe àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.+ 29  Tí Ọlọ́run bá dákẹ́, ta ló lè dá a lẹ́bi? Tó bá fojú pa mọ́, ta ló lè rí i? Ì báà jẹ́ sí orílẹ̀-èdè tàbí èèyàn, ibì kan náà ló máa já sí, 30  Kí ẹni tí kò mọ Ọlọ́run* má bàa ṣàkóso,+Tàbí kó dẹkùn fún àwọn èèyàn. 31  Ṣé ẹnikẹ́ni máa sọ fún Ọlọ́run pé,‘Mo ti jìyà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò ṣẹ̀ rárá;+ 32  Jẹ́ kí n mọ ohun tí mi ò mọ̀;Tí mo bá ti ṣe ohunkóhun tí kò dáa, mi ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́’? 33  Ṣé ó máa san ọ́ lẹ́san bí o ṣe fẹ́, nígbà tó jẹ́ pé o kọ ìdájọ́ rẹ̀? Ìwọ lo máa pinnu, kì í ṣe èmi. Torí náà, sọ ohun tí o mọ̀ dáadáa fún mi. 34  Àwọn tó ní òye,* ọlọ́gbọ́n èyíkéyìí tó ń gbọ́ mi,Máa sọ fún mi pé, 35  ‘Jóòbù ń sọ̀rọ̀ láìní ìmọ̀,+Kò sì fi ìjìnlẹ̀ òye sọ̀rọ̀.’ 36  Kí a* dán Jóòbù wò títí dé òpin,Torí èsì rẹ̀ dà bíi ti àwọn èèyàn burúkú! 37  Ó fi ọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀;+Ó pàtẹ́wọ́ níwájú wa tẹ̀gàntẹ̀gàn,Ó sì sọ̀rọ̀ púpọ̀ sí Ọlọ́run tòótọ́!”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “òkè ẹnu.”
Ní Héb., “ọkàn.”
Tàbí “ayé tá à ń gbé.”
Ní Héb., “fọkàn.”
Ní Héb., “ẹran ara.”
Tàbí “ka èèyàn pàtàkì sí ju ẹni rírẹlẹ̀.”
Tàbí “apẹ̀yìndà.”
Ní Héb., “ọkàn.”
Tàbí kó jẹ́, “Bàbá mi, kí a.”