Jóòbù 18:1-21
18 Bílídádì+ ọmọ Ṣúáhì fèsì pé:
2 “Ìgbà wo lẹ ò ní sọ̀rọ̀ báyìí mọ́?
Ẹ lo òye, ká lè wá sọ̀rọ̀.
3 Kí ló dé tí ẹ̀ ń fojú ẹranko wò wá,+Tí ẹ sì kà wá sí òpònú?*
4 Tí o bá tiẹ̀ fa ara* rẹ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ torí inú tó ń bí ọ,Ṣé a máa pa ayé tì nítorí rẹ ni,Àbí àpáta máa ṣí kúrò ní àyè rẹ̀?
5 Àní, a máa pa iná ẹni burúkú,Ọwọ́ iná rẹ̀ kò sì ní tàn.+
6 Ó dájú pé ìmọ́lẹ̀ inú àgọ́ rẹ̀ máa di òkùnkùn,A sì máa fẹ́ fìtílà tó wà lórí rẹ̀ pa.
7 Ìrìn tó ń fi tagbáratagbára rìn dín kù,Ìmọ̀ràn ara rẹ̀ sì máa gbé e ṣubú.+
8 Torí ẹsẹ̀ rẹ̀ máa mú un wọnú àwọ̀n,Ó sì máa rìn gbéregbère wọnú àwọn okùn rẹ̀.
9 Pańpẹ́ máa mú un ní gìgísẹ̀;Ìdẹkùn á sì mú un.+
10 Okùn kan ti wà nípamọ́ dè é lórí ilẹ̀,Pańpẹ́ sì wà lójú ọ̀nà rẹ̀.
11 Jìnnìjìnnì bò ó yí ká,+Ó sì ń sá tẹ̀ lé e ní ẹsẹ̀ rẹ̀.
12 Okun tán nínú rẹ̀,Àjálù+ sì máa mú kó ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́.*
13 Awọ ara rẹ̀ jẹ dà nù;Àìsàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí tó lágbára jù* jẹ apá àti ẹsẹ̀ rẹ̀ run.
14 Wọ́n fà á kúrò nínú àgọ́ rẹ̀ tí ààbò wà,+Lọ sọ́dọ̀ ọba ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀.*
15 Àwọn àjèjì* á máa gbé inú àgọ́ rẹ̀;A máa fọ́n imí ọjọ́ sórí ilé rẹ̀.+
16 Gbòǹgbò rẹ̀ máa gbẹ lábẹ́ rẹ̀,Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì máa rọ lórí rẹ̀.
17 Wọn ò ní rántí rẹ̀ mọ́ ní ayé,Wọn ò sì ní mọ orúkọ rẹ̀* ní àdúgbò.
18 Wọ́n máa lé e kúrò nínú ìmọ́lẹ̀ sínú òkùnkùn,Wọ́n sì máa lé e kúrò ní ilẹ̀ tó ń méso jáde.
19 Kò ní ní ọmọ àti àtọmọdọ́mọ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀,Kò sì ní sí ẹni tó máa yè bọ́ níbi tó ń gbé.*
20 Tí ọjọ́ rẹ̀ bá dé, àwọn èèyàn tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn máa bẹ̀rù,Jìnnìjìnnì sì máa bo àwọn èèyàn tó wà ní Ìlà Oòrùn.
21 Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àgọ́ ẹni burúkú nìyíÀti ibùgbé ẹni tí kò mọ Ọlọ́run.”

