Jóòbù 39:1-30

  • Àwọn ẹran tí Ọlọ́run dá jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn ò mọ nǹkan kan (1-30)

    • Àwọn ewúrẹ́ orí òkè àti àgbọ̀nrín (1-4)

    • Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó (5-8)

    • Akọ màlúù inú igbó (9-12)

    • Ògòǹgò (13-18)

    • Ẹṣin (19-25)

    • Àṣáǹwéwé àti idì (26-30)

39  “Ṣé o mọ ìgbà tí àwọn ewúrẹ́ orí òkè máa ń bímọ?+ Ṣé o ti rí àgbọ̀nrín tó ń bímọ rí?+   Ṣé o máa ń ka iye oṣù tí wọ́n máa ń lò? Ṣé o mọ ìgbà tí wọ́n ń bímọ?   Wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ tí wọ́n bá ń bímọ,Ìrora ìrọbí wọn á sì lọ.   Àwọn ọmọ wọn máa wá lágbára, wọ́n á sì dàgbà nínú pápá gbalasa;Wọ́n á jáde lọ, wọn ò sì ní pa dà sọ́dọ̀ wọn mọ́.   Tá ló tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó* sílẹ̀ lómìnira,+Ta ló sì tú okùn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó?   Mo ti fi aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ṣe ilé rẹ̀,Mo sì ti fi ilẹ̀ iyọ̀ ṣe ibùgbé rẹ̀.   Ó ń pẹ̀gàn rúkèrúdò tó wà nínú ìlú;Kò sì gbọ́ ariwo darandaran.   Ó ń rìn kiri lórí àwọn òkè, ó ń wá ibi ìjẹko,Ó ń wá gbogbo ewéko tútù.   Ṣé akọ màlúù igbó máa fẹ́ sìn ọ́?+ Ṣé ó máa sun ilé ẹran* rẹ mọ́jú? 10  Ṣé o lè fi okùn fa akọ màlúù igbó láàárín poro,Àbí ó lè tẹ̀ lé ọ lọ túlẹ̀* ní àfonífojì? 11  Ṣé o lè fọkàn tán agbára ńlá rẹ̀,Kí o sì jẹ́ kó bá ọ ṣe iṣẹ́ alágbára? 12  Ṣé o máa gbára lé e pé kó gbé irè oko* rẹ wá,Ṣé ó sì máa kó o jọ sí ibi ìpakà rẹ? 13  Ògòǹgò ń fi ayọ̀ lu ìyẹ́ rẹ̀ pìpì,Àmọ́ ṣé a lè fi àwọn ìyẹ́ tó fi ń fò àti ìyẹ́ tó bo ara rẹ̀ wé ti ẹyẹ àkọ̀?+ 14  Torí ilẹ̀ ló máa ń fi ẹyin rẹ̀ sí,Ó sì ń mú kí wọ́n móoru nínú iyẹ̀pẹ̀. 15  Ó gbàgbé pé àwọn ẹsẹ̀ kan lè tẹ̀ wọ́n fọ́,Tàbí pé ẹran igbó lè tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀. 16  Ó ń ṣe àwọn ọmọ rẹ̀ ṣúkaṣùka, bí ẹni pé òun kọ́ ló bí wọn;+Kò bẹ̀rù pé làálàá òun lè já sí asán. 17  Torí Ọlọ́run ò fún un ní* ọgbọ́n,Kò sì pín òye kankan fún un. 18  Àmọ́ tó bá dìde tó sì gbọn ìyẹ́ rẹ̀ pìpì,Ó máa fi ẹṣin àti ẹni tó gùn ún rẹ́rìn-ín. 19  Ṣé ìwọ lo fún ẹṣin ní agbára?+ Àbí ìwọ lo fi irun* tó ń fẹ́ lẹ́lẹ́ wọ ọrùn rẹ̀ láṣọ? 20  Ṣé o lè mú kó fò sókè bíi tata? Bó ṣe ń fọn imú rẹ̀ lọ́nà tó gbayì ń kó jìnnìjìnnì báni.+ 21  Ó ń fi àtẹ́lẹsẹ̀ talẹ̀ ní àfonífojì, ó sì ń bẹ́ tagbára-tagbára;+Ó ń lọ tààràtà sójú ogun.*+ 22  Ó rí ìbẹ̀rù, ó rẹ́rìn-ín, ohunkóhun ò sì já a láyà.+ Kì í torí idà yíjú pa dà. 23  Apó ń mì pẹkẹpẹkẹ sí i,Ọ̀kọ̀ àti ẹ̀ṣín ń tàn yanran. 24  Bí ara rẹ̀ ṣe ń yá gágá, tó sì ń gbọn ara nù, ó ń bẹ́ gìjà síwájú,*Kò lè dúró jẹ́ẹ́* tí wọ́n bá fun ìwo. 25  Tí ìwo bá dún, á figbe ta! Ó ń gbóòórùn ìjà láti òkèèrè,Ó sì ń gbọ́ ariwo àwọn ọ̀gágun àti igbe ogun.+ 26  Ṣé òye rẹ ló ń mú kí àṣáǹwéwé fò lọ sókè réré,Tó sì ń na ìyẹ́ rẹ̀ sí apá gúúsù? 27  Àbí ìwọ lò ń pàṣẹ fún idì, tó fi ń fò lọ sókè,+Tó ń kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ síbi tó ga fíofío,+ 28  Tó ń sun orí òkè tó dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ mọ́jú,Tó ń gbé ibi ààbò rẹ̀ níbi àpáta gbágungbàgun?* 29  Látibẹ̀ ló ti ń wá oúnjẹ;+Ojú rẹ̀ ń ríran jìnnà réré. 30  Àwọn ọmọ rẹ̀ ń fa ẹ̀jẹ̀ mu;Ibi tí òkú bá sì wà, ibẹ̀ ló máa ń wà.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí oríṣi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní onager.
Tàbí “ibùjẹ ẹran.”
Tàbí “fọ́ ilẹ̀.”
Ní Héb., “irúgbìn.”
Ní Héb., “mú kó gbàgbé.”
Tàbí “gọ̀gọ̀.”
Ní Héb., “Ó ń jáde lọ pàdé ìhámọ́ra.”
Ní Héb., “gbé ilẹ̀ (ayé) mì.”
Tàbí kó jẹ́, “Kì í gbà gbọ́.”
Ní Héb., “gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àpáta.”