Jóòbù 3:1-26
3 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jóòbù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ó sì ń fi ọjọ́ tí wọ́n bí i gégùn-ún.*+
2 Jóòbù sọ pé:
3 “Kí ọjọ́ tí wọ́n bí mi + ṣègbé,Àti òru tí ẹnì kan sọ pé: ‘Wọ́n ti lóyún ọkùnrin kan!’
4 Kí ọjọ́ yẹn ṣókùnkùn.
Kí Ọlọ́run lókè má ka ọjọ́ yẹn sí;Kí ìmọ́lẹ̀ má tàn sórí rẹ̀ rárá.
5 Kí òkùnkùn biribiri* gbà á pa dà.
Kí òjò ṣú bò ó.
Kí ohunkóhun tó ń mú ojúmọ́ ṣókùnkùn dẹ́rù bà á.
6 Kí ìṣúdùdù gba òru yẹn;+Kó má ṣe yọ̀ láàárín àwọn ọjọ́ tó wà nínú ọdún,Kí wọ́n má sì kà á mọ́ àwọn oṣù.
7 Àní, kí òru yẹn yàgàn!
Ká má ṣe gbọ́ igbe ayọ̀ kankan ní òru yẹn.
8 Kí àwọn tó ń fi ọjọ́ gégùn-ún fi í gégùn-ún,Àwọn tó lè mú kí Léfíátánì*+ sọ jí.
9 Kí àwọn ìràwọ̀ rẹ̀ ṣókùnkùn ní ìdájí;Kó dúró de ìmọ́lẹ̀, àmọ́ kí ìrètí rẹ̀ já sí asán,Kó má sì rí ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀.
10 Torí kò ti àwọn ilẹ̀kùn ilé ọlẹ̀ ìyá mi;+Kò sì pa ojú mi mọ́ kúrò nínú wàhálà.
11 Kí ló dé tí mi ò kú nígbà tí wọ́n bí mi?
Kí ló dé tí mi ò ṣègbé nígbà tí mo jáde látinú ikùn?+
12 Kí ló dé tí orúnkún tó gbà mí fi wà,Tí ọmú tí màá mu sì wà?
13 Torí mi ò bá máa dùbúlẹ̀ báyìí láìsí ìyọlẹ́nu;+Mi ò bá máa sùn, kí n sì máa sinmi+
14 Pẹ̀lú àwọn ọba ayé àti àwọn agbani-nímọ̀ràn wọn,Tí wọ́n kọ́ àwọn ibi tó ti di àwókù báyìí fún ara wọn,*
15 Tàbí pẹ̀lú àwọn ìjòyè tó ní wúrà,Àwọn tí fàdákà kún ilé wọn.
16 Àbí kí ló dé tí oyún mi ò ti bà jẹ́ kí wọ́n tó mọ̀,Bí àwọn ọmọ tí kò rí ìmọ́lẹ̀ rárá?
17 Ibẹ̀ ni àwọn ẹni burúkú pàápàá ti bọ́ lọ́wọ́ ìdààmú;Ibẹ̀ ni àwọn tí kò lókun ti ń sinmi.+
18 Ibẹ̀ ni ara ti tu àwọn ẹlẹ́wọ̀n pa pọ̀;Wọn ò gbọ́ ohùn ẹni tó ń fipá kó wọn ṣiṣẹ́.
19 Ẹni kékeré àti ẹni ńlá ò jura wọn lọ níbẹ̀,+Ẹrú sì dòmìnira lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ̀.
20 Kí ló dé tó fún ẹni tí ìyà ń jẹ ní ìmọ́lẹ̀,Tó sì fún àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn*+ ní ìyè?
21 Kí ló dé tí wọ́n ń retí ikú, àmọ́ tí kò dé?+
Wọ́n ń wá a ju bí wọ́n ṣe ń wá ìṣúra tó fara pa mọ́ sínú ilẹ̀,
22 Àwọn tí inú wọn ń dùn gidigidi,Tí wọ́n ń yọ̀ nígbà tí wọ́n rí sàréè.
23 Kí ló dé tó fún ẹni tó ṣìnà ní ìmọ́lẹ̀,Ẹni tí Ọlọ́run ti sé mọ́?+
24 Ẹ̀dùn ọkàn ti dípò oúnjẹ mi,+Ìkérora mi+ sì ń tú jáde bí omi.
25 Torí ohun tí mo bẹ̀rù ti dé bá mi,Ohun tó sì ń já mi láyà ti ṣẹlẹ̀ sí mi.
26 Mi ò ní àlàáfíà, ọkàn mi ò balẹ̀, mi ò sì sinmi,Síbẹ̀, wàhálà ò yéé dé bá mi.”

