Jóòbù 4:1-21

  • Ọ̀rọ̀ tí Élífásì kọ́kọ́ sọ (1-21)

    • Ó bẹnu àtẹ́ lu ìwà títọ́ Jóòbù (7, 8)

    • Ó sọ ohun tí ẹ̀mí kan bá a sọ (12-17)

    • ‘Ọlọ́run ò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀’ (18)

4  Élífásì+ ará Témánì wá fèsì pé:   “Tí ẹnì kan bá fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀, ṣebí wàá ní sùúrù? Àbí ta ló lè dákẹ́ kó má sọ̀rọ̀?   Òótọ́ ni pé o ti tọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn sọ́nà,O sì máa ń fún àwọn ọwọ́ tí kò lágbára lókun.   Ọ̀rọ̀ rẹ máa ń gbé ẹnikẹ́ni tó bá kọsẹ̀ dìde,O sì máa ń fún àwọn tí orúnkún wọn yẹ̀ lókun.   Àmọ́ ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ báyìí, ó sì wá mu ọ́ lómi;*Ó kàn ọ́, ìdààmú sì bá ọ.   Ṣé ìbẹ̀rù tí o ní fún Ọlọ́run kò fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀ ni? Ṣé ìwà títọ́+ rẹ ò fún ọ ní ìrètí ni?   Jọ̀ọ́ rántí: Aláìṣẹ̀ wo ló ṣègbé rí? Ìgbà wo ni àwọn adúróṣinṣin pa run rí?   Ohun tí mo rí ni pé àwọn tó ń túlẹ̀ láti gbin* ohun tó burúÀti àwọn tó ń gbin wàhálà máa kórè ohun tí wọ́n bá gbìn.   Èémí Ọlọ́run mú kí wọ́n ṣègbé,Ìbínú rẹ̀ tó le sì mú kí wọ́n wá sí òpin. 10  Kìnnìún ń ké ramúramù, ọmọ kìnnìún sì ń kùn,Àmọ́ eyín àwọn kìnnìún tó lágbára* pàápàá kán. 11  Kìnnìún ṣègbé torí kò rí ẹran pa jẹ,Àwọn ọmọ kìnnìún sì tú ká. 12  A sọ ọ̀rọ̀ kan fún mi ní àṣírí,A sì sọ ọ́ sí mi létí wúyẹ́wúyẹ́. 13  Nínú ìran tí mo rí ní òru, tó ń da ọkàn láàmú,Nígbà tí àwọn èèyàn ti sùn lọ fọnfọn, 14  Mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n rìrì lákọlákọ,Ìbẹ̀rù bò mí wọnú egungun. 15  Ẹ̀mí kan kọjá lójú mi;Irun ara mi dìde. 16  Ó wá dúró sójú kan,Àmọ́ mi ò dá a mọ̀. Ohun kan wà níwájú mi;Gbogbo nǹkan pa rọ́rọ́, mo wá gbọ́ ohùn kan tó sọ pé: 17  ‘Ṣé ẹni kíkú lè jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run lọ? Ṣé ẹnì kan lè mọ́ ju Ẹni tó dá a lọ?’ 18  Wò ó! Kò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,Ó sì ń wá àṣìṣe àwọn áńgẹ́lì* rẹ̀. 19  Mélòómélòó wá ni àwọn tó ń gbé ilé alámọ̀,Tí ìpìlẹ̀ wọn wà nínú iyẹ̀pẹ̀,+Tí wọ́n rọrùn láti tẹ̀ rẹ́ bí òólá!* 20  A tẹ̀ wọ́n rẹ́ pátápátá láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀;Wọ́n ṣègbé títí láé, ẹnì kankan ò sì kíyè sí i. 21  Ṣebí wọ́n dà bí àgọ́ tí wọ́n fa okùn rẹ̀ yọ? Wọ́n kú láìní ọgbọ́n.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “àárẹ̀ sì mú ọ.”
Tàbí “hùmọ̀.”
Tàbí “àwọn ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Tàbí “òjíṣẹ́.”
Tàbí “kòkòrò.”